AROKO LETA AIGBEFE
OSE KEJI
AROKO LETA AIGBEFE
Leta kiko je ona kan pataki ti a n lo lati ranse si ara eni. Kiko ni a maa n ko o. Ko si ohun ti a o le ko si eniyan afi eyi ti a ko fe ko. A le pin leta kiko si orisii ona meji pataki. Akoko ni leta gbefe (informal letter) nigba ti ekeji je leta aigbefe (formal letter).
Leta gbefe ni leta ti a n ko si eni ti o sunmoni bi baba, iya, aburo, egbon. Leta aigbefe/ alaigbefe ni eyi ti ofin de pe o gbodo tele eto tabi ilana kan pato ti ijoba fowo si. Irufe leta yii ni leta ti a n ko si ile ise ijoba, eyi ti a n ko si ile ise nlanla, leta si ijoba ibile, leta iwase, leta igbaaye lenu ise abbl.
ETO IGBEKALE LETA AIGBEFE
- Adiresi
- Ibere
- Ori
- Ikini
- Koko oro
- Ipari/igunle.
Adiresi leta aigbefe pin si orisii meji. Adiresi eni ti o n ko leta ati adiresi ibi ti leta nlo (eni ti a n ko leta si). Fun apeere:
12, Opopona Ayedaade,
Ibudoko U-Turn,
Abule Egba
Eko.
10-08-2014.
Oga Ile Iwe,
Good Shepherd School,
3, Opopona Olayinka, Moroga,
Meiran.
Oga Agba,
Adiresi eni ti o n ko leta yoo wa ni oke apa otun nigba ti adiresi eni ti a n ko leta si yoo wa ni oke apa osi. Leyin eyi ni ibere ati ori pelu awon igbese to ku. Ki i se dandan ni ki a ki eniyan ninu leta aigbefe bakan naa ni a gbodo kiyesi awon oro awada/alufasansi ninu leta yii. A o ki n se awada ninu leta aigbefe.
IGBELEWON
- Ko adiresi ile re sile.
- Ko adiresi ijoba ibile re sile.
AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2005)Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (S.S .S.1) oju iwe 16- 21 University Press Plc.
AWON ORISA ATI EEWO
Eewo je ohun ti eniyan ko gbodo se. O fere je pe gbogbo awon orisa ti won n bo ni ile Yoruba lo ni ohun ti won fe ati ohun ti won ko fe. Ohun ti won fe le je ohun jije tabi mimu nigba ti ohun ti won ko fe le je iwa tabi isesi. Awon ohun ti won ko fe yii ni a n pe ni eewo. Die lara won ni wonyi:
ORISA EEWO TO JE MO JIJE/MIMU EEWO TO JE MO IWA/ISESI
Obatala Obatala ko gbodo mu emu funfun tabi Oti aisooto, iwa eeri
Ogun eke sise, ole jija,agbere, ile dida, iro pipa
Sango won ki I je ewa sese, eku ago ati eso.
won ko gbodo mu siga,won ko gbodo gbe ina ka ori Igi abo
Oya oloya ko gbodo je eran agbo agbere sise
Orisa ibeji ibeji ko gbodo je eran obo lanbe ole jija
Elegbara/esu elesu ko gbodo lo adi tabi yanko ireje, ole, omugo
Orisa oko olusin ko gbodo je isu tuntun lai ti olusin ko gbodo gba aje
la isu odun fun orisa oko
Ifa onifa ko gbodo je ejo,won ko gbodo fe ireje, iro pipa, olusin ko
gbodo fe iyawo ara won. Adi tabi yanko
Gelede onigelede ko gbodo je ejo ..................
Buuku won ki i je ejo ole jija, eke sise.
Ayelala .................. ole jija, iro pipa, ile dida.
IGBELEWON
- Ki ni eewo jije/mimu sango
- Ki ni iwa /isesi ti Oya korira
AKATILEWA
Oyebamji Mustapha(2002) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.3) oju iwe 120-127 UniversityPress Plc.
IFAARA LORI LITIRESO ALOHUN TI A N FI ORO INU WON DA WON MO.
Awon litireso wonyi ki i ni isori kan taara, won o je mo esin bee naa ni won o je mo ayeye lo ju. Apeere won ni oriki, ofo, ese ifa, itandonwe, oro akonilenu, aalo, ewidowe, ede asiko abbl.
A Oriki Orile (family name/praise): Oriki orile ni ewi alohun ti o da lori baba nla eni ati ibi ti won ti se wa. Apeere oriki orile ni onikoyi, Oluoje, Oko irese, Ajisola, Erin, Opomulero, Olofa, Ologbin-in Olufe, Iloko abbl.
B OFO (incantation): Ofo je oro agbara ti awon Yoruba maa n lo pelu oogun. Ofo ni o n fi igbagbo awon Yoruba han ninu agbara oro. Aarin awon adahunse ati onisegun ni o ti wopo. Awon nnkan ti a fi maa n da mo ni: A ki i, oro ase, ebe, awitunwi, iforodara, afiwe.
D ESE IFA (ifa divination ): Awon ni oro agbara ti awon onifa maa n lo. Awon babalawo/onifa ni o maa n da ifa. Awon ti won maa n da ifa maa n wo aso funfun, bata funfun pelu inu mimo. Awon ohun ti a fi maa n da ese ifa ni: Adia fun, ebo riru, awon oruko emi airi.
E ORO AKONILENU; awon oro ti o soro sare pe ni oro akonilenu. Apeere oro akonilenu ni: obo n gbe obo gun ope, Alira n lora rela, Mo je dodo nido ma wa fi owo dodo pa omo onidodo ni idodo.
IGBELEWON
- Awon ewi alohun wo ni a maa n fi oro inu won da won mo?
- Ko oriki orile marun-un sile.
- Salaye perete lori ofo.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 55-58 Copromutt (publishers) Nigeria Limited
APAPO IGBELEWON
- Ki ni eewo jije/mimu sango
- Ki ni iwa /isesi ti Oya korira
- Ki ni eewo jije/mimu sango
- Ki ni iwa /isesi ti Oya korira
- Awon ewi alohun wo ni a maa n fi oro inu won da won mo?
- Ko oriki orile marun-un sile.
- Salaye perete lori ofo.
ATUNYEWO ISE
- Fun awon gbolohun yii ni apeere mejimeji: gbolohun abode, Olopo Ooro-Ise, Alakanpo.
ISE ASETILEWA
- Leta …….ni leta iwase. (a) ore (b) gbefe (d) alaigbefe.
- Ibi ti adiresi eni ti a n ko leta si maa n wa ni….. (a) isale leta patapata ni apa osi (b) oke leta ni apa otun (d) oke leta ni apa osi
- Adiresi eni ti n ko leta maa n wa ni ….. (a) isale leta ni apa otum (b) oke leta ni apa osi (d) oke leta ni apa otun
- ……. je okan lara ewi ti a n fi oro inu won da won mo (a) rara (b) bolojo (d) ofo
- Orisa wo ni ki I mu emu funfn tabi oti (a) ogun (b) obatala (d) ifa.
APA KEJI
- Ko adiresi ile ibi ti o n gbe ati adiresi ijoba ibile re sile
- Ko oriki re sile
- Ko eewo sango ati orisa oko sile/