HIHUN ORIISIRISSI AWE GBOLOHUN PO DI ODIDI GBOLOHUN
OSE KIN-IN-NI
HIHUN ORIISIRISSI AWE GBOLOHUN PO DI ODIDI GBOLOHUN
AKOON: ODIDI GBOLOHUN
AWE GBOLOHUN
Gbolohun ni iso ti o kun lati ero okan eni wa TABI ki a so wi pe Gbolohun ni ipede ti o kun pelu itumo ti o si ni ise ti o n se. Bi a ba fe ba enikan soro tabi ti a ba fe se iroyin, a maa n se amulo orisii eya gbolohun bi: gbolohun eleyo oro ise, olopo oro ise,alakanpo, ibeere abbl. Ki a ranti pe ninu gbolohun kan, oro ise se pataki nibe. Fun apeere ( odidi gbolohun).
Wa.
Ade sun si ori aga.
Mo wa nile.
Kunle je eba ni ana.
Ti a ba wo awon gbolohun oke yii a o ri wi pe gbogbo won ni won ni itumo kikun. Nitori naa awon wonyi ni apeere odidi gbolohun. Awe gbolohun ni apa kan odidi gbolohun. Laisi odidi gbolohun ko le si awe gbolohun nitori pe ara odidi gbolohun ni a ti fa a yo. Orisii awe gbolohun ti a ni ni olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe. Ninu odidi gbolohun a le ri awe gbolohun meji tabi ju bee lo. Fun apeere.
Mo je eba ni agogo meje.
Mo ti lo ki o to de.
Ti a ba wo awon gbolohun yii daadaa a o ri wi pe gbolohun alakoko, a le pin si meji: Mo je eba ati ni agogo meje. Ni gbolohun keji, a ri Mo ti lo ati ki o to de. Ege kookan yii ni a pe ni awe gbolohun ninu odindi gbolohun.
Mo ti lo ki ore mi to de
(Olori awe gbolohun) ( awe gbolohun afarahe )
Mo je eba ni agogo meje
(olori awe gbolohun) ( awe gbolohun afarahe)
IGBELEWON
- Ki ni gbolohun?
- Ki ni awe gbolohun?
- Iyato wo lo wa laarin gbolohun ati awe gbolohun?
AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta J S S 3 oju iwe 10-12 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.
ORIN ETIYERI
Orin idaraya ni orin etiyeri, won maa n gbe eku sori ni bi i ti eegun, eni to gbe eku sori ni yoo maa le orin ti awon yoku a si maa gbe e. Won fi n tu asiri iwa ibaje. A si maa n ri oro awada ati oro alufasansi nibe. Orin yii wopo ni agbegbe ilu Oyo. Apeere.
ORIN ETIYERI.
LILE: E ma a pe yoo se
EGBE: A a se
LILE: Ema a pe yoo se
EGBE: A a se
LILE: Ode roko ode peran
EGBE: A a se
LILE: Eran kilode pa
EGBE: A a se………… .
DADAKUADA
Orin amuludun to ni oriki, iyin, ilu ati orin ninu ni dadakuada. O wopo ni adugbo igbomina/Ilorin. Bi olori ba ti n le orin ni enikan yoo maa gbe. O maa n kun fun oro apanilerin, won fi n ki eniyan tabi kilo iwa ibaje. Won maa n lo nibi igbeyawo, isile isomoloruko, ayeye oku agba, iwuye. Won maa n lo ilu gangan bi meta nibe. Apeere
Ile to jo ti olonginni joha le
Aso lologinni mabi sokoto
Abinsi, mongani duniyan………..
IGBELEWON
- Salaye perete lori orin etiyeri
- Salaye perete lori dadakuada.
AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2004) New Simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 10-12 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.
ASA TO SUYO NINU ORIN ETIYERI ATI DADAKUADA
ORIN ETIYERI
Orin, ilu ati ijo
Iwure/epe/eebu.
Awada.
Ikilo iwa ibaje.
Koriya.
DADAKUADA
Orin, ilu ati ijo
Awada/eebu
Iyin
Oriki
Ikilo iwa
Koriya.
IGBELEWON
- Awon asa wo lo suyo ninu orin etiyeri?
- Awon asa wo lo suyo ninu dadakuada?
APAPO IGBELEWON
- Ki ni gbolohun?
- Ki ni awe gbolohun?
- Iyato wo lo wa laarin gbolohun ati awe gbolohun?
- Awon asa wo lo suyo ninu orin etiyeri?
- Awon asa wo lo suyo ninu dadakuada?
- Adugbo wo ni orin etiyeri ti wopo?
AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 44-50 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.
ATUNYEWO ISE
- Ko aroko lori bi o lo isinmi keresimesi ti o koja.
ISE ASETILEWA
- Ewo lo kun ju lati gbe ero okan eni kale? (a) oro (b) awe gbolohun (d) odidi gbolohun.
- Ewo ni ki i se orisii gbolohun Yoruba (a) olopo oro ise (b) alakanpo (d) alatunto
- Awe gbolohun wo lo le da duro bi odidi gbolohun (a) olori (b) afarahe (d) asaponle.
- Adugbo wo ni orin etiyeri ti wopo ? (a) Ekiti (b) Oyo (d) Osun.
- Asa wo lo maa suyo ninu dadakuada? (a) esin (b) eto oselu (d) awada
APA KEJI
- Iyato wo lowa laarin odidi gbolohun ati awe gbolohun?
- Awon asa wo lo suyo ninu orin etiyeri ati dadakuada?