ORI-ORO : Awon Eya Ara Ifo
OSE KINNI
ORI-ORO : Awon Eya Ara Ifo
-Eyi ti a le fojuri ati eyi ti a ko le fojuri
-Afipe asunsi ati akanmole.
Akoonu
Eya ara ifo-;eyi ni awon eya arati won n sise papo lati gbeiro-ede jade.
Eya ara ifo-;eyi ni gbogbo awon eya ara ti o kopa nigba ti a ba n soro.
Apeere awon eya ara ifo ni;
Ahon,,ete,,afase, eyin, erigi,komookun,tan-an-na,olele,aja-enu,gogongo,alafo tan-an-na abbl.
Isori eya ara ifo
Eya ara ifo pin si ona meji
1.Awon eya ara ifo ti a le fojuri
ii.Awon eya ara ifo ti a ko le fojuri.
Eya ara ifo ti a le fojuri-;eyi ni awon eya ara ti a le fojuri paapaa ti a ba lo digi.
Ap;
Iwaju ahon
Aarin ahon
Eyin ahon
Ete oke
Ete isale
Olele
Afase
Erigi
Eyin oke abbl.
ii.Awon eya ara ifo ti a ko le fojuri-;eyi ni awon eya ara ifo ti a ko le fojuri,ti won wa ninu ikun wa.
Ap
Edofooro
Eka komookun
Tan-an-na
Inu gogongo
Kaa ofun
Afipe
Afipe-;eyi ni gbogbo awon eya ara ti o kopa nigba ti a ba n soro.afipe pin si ona meji
Afipe asunsi ati
akanmole.
Afipe asunsi-eyi ni awon eya ara ifo to le sun soke tabi sodo nigba ti a ba n soro.obere latiete isale wa si agbondo.
Apeere afipe asunsi ni;
Eyin isale
Ete isale
Iwaju ahon
Eyin ahon
Olele
Aarin ahon
Afipe akanmole;-Eyi ni awon eya ara ti ko le sun kuro ni oju kan,ti won maa n duro gbari nigba ti a ba n soro .o bere lati oke enu wa apeere
Ete oke
Eyin oke
Erigi oke
Afase
Kaa imu
Aja enu
IGBELEWON
Daruko eya ara ifo mewaa.
ASA
ORI-ORO-;Owe ile Yoruba
AKOONU
Yoruba bo won ni ‘Owe ni esin oro,oro ni esin owe,boro ba sonu owe ni a fi n wa.
Owe je ijinle tabi koko ewa-ede ti o n fi asa,ero,ati ise awon Yoruba han.
Owe wulo pupo ni opolopo ona
Opolopo ona ni owe gba wulo, awon ohun ti a n lo owe fun niwonyii;
Owe ikilo
Owe ibawi
Owe efe
Owe imoran/isiri.
OWE IKILO.
Owe ikilo ni a n lo lati kilo iwa fun tomode –tagba.Bi omode kan ba n kegbe buruku awon,awon agbalagba le pe iru omo bee ki won wi fun-un pe ki o sora nitori pe;-
-Agutan ti o ba ba aja rin yoo jegbe.
- Egbe buburu n ba iwa rere je..ohun ti won n wi fun omo bee nipe won kaa si omo rere sugbon o gbodo yera fun awon oniwa buburu.
- Arinrin gbere niyoo moye dele,asure tete kole roye je.
- A kii fi ikanju labe gbigbona.
- Kirakita ko mola,ka sise bi eru koda nnkan.
- A kii korira atokun kadigbo lu eegun.
- Puro ki o niyi,ete ni n mu wa.
LITIRESO
IGBELEWON
1.Kin ni afipe?
b.Salaye afipe asunsi ati akanmole.
2.kin ni owe?
b.Daruko orisii owe merin ti o mo.
IWE AKATILEWA
Imo,Ede,Asa Ati Litireso Yoruba ss2 o.i 1-5.
ISE ASETILEWA
1.______ ni awon eya ara ti a n lo lati gbe iro-ede jade. [a]enu [b]eya ara ifo [d]eya ara.
2.Apeere eya ara ti a le fojuri ni -------- [a]Edofooro [b]gogongo [d]ete
3.Ona --------- ni litireso pin si [a]kan [b]meji [d]meta
4.Eya ara ti o le sun kuro ni ojukan nigba ti a ba n soro ni____ .[a]inu gogongo [b]asunsi [d]akanmole.
5.________ ni esin oro,oro lesin owe.[a]akanlo-ede ]b]owe [d] ijinle oro.
APA KEJI
1’Kin ni eya ara ifo
b.Daruko eya ara ifo mewaa.
2.Daruko ohun merin ti a n lo owe fun.