Skip to content

We use essential cookies to sign you in and remember your settings. With your permission we also use analytics cookies to understand how the site is used. See our privacy policy or fine-tune this anytime at cookie settings.

SubjectFree lesson

ORO – AYALO

ClassNotes Team 5 MIN READUPDATED 5 JUL 2026

OSE KEJI

ORO – AYALO

 

AKOONU

Oro – Ayalo: ni awon oro ajeji ti a maa n ya wonu ede Yoruba lati inu ede miiran tabi ki a so wipe Oro ayalo ni mimu oro lati inu ede kan wo inu ede miiran lona ti pipe ati lilo re yoo fi wa ni ibamu pelu ede ti a mu-un wo. Oro – ayalo maa n mu ki ede dagba. Bakan naa, o maa n je ki oruko wa fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba n sese n wo awujo wa

Yoruba ni ilana meji ti won n gba ya oro wo inu ede Yoruba, awon naa ni

-         Ilana afetiya

-         Ilana afojuya

ILANA AFETIYA: Eyi ni pipe oro ayalo ni ona to sunmo bi awon elede se n pe oro gan-an:

Bible -          Baibu

Peter  -        Pita

Table  -        Tebu

Esther -        Esita

Deacon -      Dikini

Council -       Kansu

Al- basal -     Alubosa

 ILANA AFOJUYA: Eyi ni kiko oro ni ilana eyi to sunmo bi awon elede se n ko.

Soldier          -        Soja

Table            -        Tabili

Peter            -        Peteru

Esther          -        Esiteri

Bible            -        Bibeli

Deacon         -        Diakoni

Paradise       -        Paradise

Hebrew        -        Heberu        

Inu awon ede wonyii ni a ti n ya oro wo inu ede Yoruba

     Ede  Geesi

     Ede  Larubawa

     Ede  Faranse

BI ORO AYALO SE WONU EDE YORUBA

Eyi ni orisiirisii ona ti oro ayalo gba wonu ede Yoruba.

  1. Esin:- nipase esin musulumi ati esin Kristi ti won mu wa fun wa ni a se ni awon oro wonyi Mosalasi, Soosi, Alijanna, Angeli Bibeli, Pasito, Kurani abbl
  1. Ajose Owo:- eyi ni ajose owo laarin Yoruba ati awon eya miiran apeere: senji, korensi, wisiki, buluu
  1. Eto Oselu:- Nipase ijoba ajeji ti awon larubawa ati Geesi mu wa ni a ti ya opolopo oro bii seria, kootu, sinato, Gomina.
  1. Asa ati Olaju:- ajumose nipa asa ati olaju mu ki a ya opolopo oro lo apeere: yigi, marede
  1. Eto Eko:- eyi ni oro ti a ya nipa eto eko apeere: tisa, boodu,

AWON IRO TI A FI N SE AARO ARA WON

i.        Ki oro ede Geesi ti a ya lo to le di ara oro inu ede Yoruba, o gbodo tele ofin ede Yoruba:

Konsonanti ki i gbeyin oro ninu ede Yoruba. Bi oro ayalo ba ni, a o fi faweli ti o ye seyin re, o le je: i, u, a tabi o, apeere:

Bread – Buredi

Gum   – Goomu

Bed    – Beedi

Shirt   – seeti

fail     – Feeli

Glass – Gilaasi

Gold   – Goolu

Class  - Kilaasi.

ii.       Yiyo konsonanti ipari oro ayalo kuro ap

Mobil            – Mobi

Moses           – Mose

Jesus            – Jesu

Lazarus        – Lasaru

 

iii.      Yiya isupo konsonanti oro- ayalo. Fifi faweli ya isupo konsonanti oro ayalo. ap

Bread –        Buredi

Milk    –        Miliiki

Tray   –        Tiree

Station –       Tesan

Belt    –        Beliiti

 

iv.      Ifiropo konsonanti ninu oro ayalo nigba miirran konsonanti oro Geesi maa n yato si ti Yoruba ap

Lazarus        – Lasaru

Church         – Soosi

Queen                    – Kunyin

Valve                     – Faafu

Stamp                    – Sitanbu/Sitanbu

Cup              – Koobu/Koopu

  1. Ami gbodo wa lori oro- ayalo
  2. Oro ayalo lo maa n bere pelu ami ohun oke
  3. Faweli aranmupe maa n bere oro ayalo

IWULO  ORO AYALO

  1. Oro ayalo lo maa n mu ki ede dagba.
  2. Nipa yiya oro lo, a maa n ri oruko fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba sese n wo awujo wa.

IGBELEWON

1.       a. Kin ni oro ayalo?

b. Daruko ona ti a n gba ya oro  o.

 

ASA

IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA OSO ATI AJE

AKOONU

Awon  Yoruba gba pe oso ati aje wa, won  tile ni igbagbo yii to bee ti o fi je pe o soro lati ri eni ti o ku, yagan tabi ti wahala sele si ti won ko ni so o mo oso ati aje.

Bakan naa awon Yoruba gbagbo pe oso ati aje ni agbara oogun ti won le fi pa eni ti won ba fe. Ewe won gbagbo pe inu ipade aje ni won ti maa n duna- an- dura bi won yoo se pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe ona meji ni okunrin fi n gba oso

         - ajogunba

       - wiwo egbe oso

bee naa ni ti aje o le je nipa ajogunba

Iyato laarin oso ati aye. Iyato to wa laarin oso ati aje ni pe awon okunrin lo maa n je oso ni gba ti awon aje je obinrin.

LITIRESO

ORIKI ORILE METADINLOGBON

IGBELEWON

  1. Kin ni igbagbo ati ero awon orile-ede Naijiria ati orile-ede miiran nipa oso ati aje?
  2. Se agekuru iran karun-un ati ikefa iwe Adakedajo.

APAPO IGBELEWON

  1. Kin ni igbagbo ati ero awon orile-ede Naijiria ati orile-ede miiran nipa oso ati aje?
  2. Se agekuru iran karun-un ati ikefa iwe Adakedajo.

IWE AKATILEWA

Adeboye Babalola et al Iwe Imodotun Yoruba SS2. o.i. 3.

Folarin Olatubosun Eto iro ati Girama Yoruba fun Sekondiri Agba. o.i 41

ISE ASETILEWA

  1. Ona _____________ ni a le gba ya oro wonu ede Yoruba (a) meji (b) meta (d) merin
  2. A ya faini wonu ede Yoruba nipase (a) eko (b) eto ilera (d) idajo
  3. A ya Bibeli nipase ilana (a) afetiya (b) afojuya (d) a kosofun wa
  4. Nje oso ati aje  wa bi? (a) beeni (b) beeko (d) a kosofun wa
  5. Ta ni Kanmi ati Alade fi owo ran? (a) Alaaji (b) Adigun (d) Omo ise re

APA KEJI

1a. Kin ni oro- ayalo?

b. Daruko ede meta ti a ti le ya oro lo

d. Daruko ona ti a le gba lati ya oro lo.

2a. Salaye igbagbo ati ero awon Yoruba nipa oso ati aje

b. Kin ni ofin yiya oro wonu ede Yoruba.