ALIFABEETI
ỜSE KIN-IN-NI
ÀKÓRÍ ISE (EDE) ALIFABEETI
A B D E E F
G GB I H J K
L M N O O P
R S S T U W
Y.
ALIFABETI
ÌRÓ FAWEELI ÌRÓ KÓŃSONANTI
Fáwéèlì Airanmupe
Faweeli Aranmupe
A Ìró Fáweli: Ìró faweeli ni àwon ìró tí èémí won kì í ní ìdíwó nígbà tí a bá n pè wón jade láti inú èdòfóró. Orisi méjì ni ìró faweeli pín sí. Àwon náà ni:
-
- Faweeli Airanmupe; a e e i o o u
- Faweeli Aranmupe; an en in on un.
B Ìro Konsonanti: Ìró kónsónántì ni àwon ìró tí ìdíwó maa n wá fún èémí ti o n ti inú èdòfóró bò nígbà tí a ba n pè wón. Gbogbo àwon ìró kónsónántì wonyi kì í gba àmì sórí àfi kónsónántì àránmúpè àsesílébù [n/m] bakan náà ni won kì í parí òrò Yorùbá. Gbogbo kónsónántì èdè Yorùbá jé méjìdínlógún[18].
ÌGBÉLÉWÒN
1 Ko faweeli àìránmúpè sílè
2 Ko faweeli aàraánmuúpeè sílè
3 Ko kónsónántì èdè Yorùbá sílè
IWE AKATILEWA
New simplified Yorùbá L1 ìwé kìn-ín-ní [Js s 1] ojú ìwé 1 láti owó S Y Adéwoyin.
AKORI ISE (ASA) ÌTÀN ÌSÈDÁLÈ YORÙBÁ.
ÀKÓÓNÚ
Odùduwà ni baba nlá àwon Yorùbá, Lámúrúdu sì ni orúko baba rè. ìtàn fi yé wa pé okùnrin kan tí orúko re n jé Lámúrúdu ni oba ìlú Mékà ni ìgbà kan ri. Abòrìsà ni oba yìí, o sì máá n rúbo sí àwon orìsa re nigba gbogbo, kódà o ni aborè fún òrìsà rè.
Ní àkókò tí a n sòrò rè yìí, èsìn mùsùlùmí sèsè wo ìlú Mékà ni, àwon omo léyìn mohammed n wàásù káàkiri gbogbo ìgboro mékà pé kí àwon ènìyàn dèyìn nidi òrìsà bíbo látàrì ìwáásù yìí, ìlú bèrè sí ní dá sí méjì àwon kan n tèlé Lámúrúdu oba won láti máa bòrìsà, àwon kan si darapò mo àwon elésin mùsùlùmí. Òkan lára àwon aborè Lámúrúdu tó n jé Bùrémò.
Ní àsikò odún òrisà , Asarà àti àwon ènìyàn re ti pese gbogbo ohun ti won fe fi bo òrisà sile nígbà tí Buremò ri pe Baba òun ti jade lo ni o ba sa iná sí gbogbo òrìsà won ti gbogbo òrisà won si jóná raurau- ìsèlè yìí ni o se okunfa ija laarin awon elesin musulumi ati àwon aborisà. Nínu ijà yìí ni Lamurudu oba kú sí.
Bayii ni Oduduwa ati àwon ènìyàn re to ku se kúrò ní ìlú Mékà wá si ile-ife tí won tedo sí tí o si di orirun àwon Yorùbá títí di òni.
ÌGBÉLÉWÒN
- Ta ni oba ìlú Mékà nigba kan ri?
- Ki ni o fa ti Odùduwà fi gbera lati ìlú Mékà wa si ile Ife
ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ
Egbe Akomolede Ati Asa Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe kin-in-ni lati owo Oju iwe 1-2
AKORI ISE: LÍTÍRÉSÒ YORÙBÁ
ÀKÓÓNÚ:-
- Ki ni a n pe ni lítírésò?
- Orisii litireso to wa
- Awon iwulo lítírésò
Èdè àyálò ni lítírésò jé. Yorùbá yá a lati inú èdè gèésì ni, nigbà ti àwon elédeè gèésì ya a lati inú èdè Latini.. Lítírésò tumo si ohun ti a ko sile sugbon ninu èdè Yorùbá ìtumò rè gbòòrò jù bee lo.
Litireso je àkójopó àsà, ogbón, ìmò, òye, ìrírí ati isé àwon Yorùbá. Òrò èsìn àti òselu ko gbeyìn nínu litireso. Èkó tó wúlò fún ìgbà gbogbo, tó sì bá ìgbà gbogbo mu ni ó máá n wà nínú lítírésò Yorùbá. Lítírésò Yorùbá pín sí ònà méjì, àwon ni:-
- Lítírésò Àpilèko:- Èyí ni àwon Lítírésò tó wà ni àkosílé tí a si n ri ka tàbí tí a le rí ko
- Lítírésò Àtenudenu: Èyi ni lítírésò tí kò sí ní àkosílè, a máá n gbà á lati enu enìkan sí enu elomiran ni. A lè pe e ni lítírésò àbáláyé tàbi lítírésò alohùn. Ohùn enu ni a fi n gbé e jade, béè sì ni pé a bá à láyé ni.
ÌWÚLÒ LÍTÍRÉSÒ
1 Ó wà fún ìdárayá
2. Ó n kóni lógbón
3. Ó kún fún ìmo ìjìnlè nípa èdè Yorùbá
4 Ó n jé ká mò nípa isèlè tó ti selè láyé àtijó
5. Ó n jé ká mo nípa àsà Yorùbá
6 Ó n tan imolè si èsìn Yorùbá
ÌGBÉLÉWÒN
1. Ki ni a n pe ni lítírésò?
2. Orisii l lítírésò mélòó ló wa?
3. So ìwúlò lítírésò méta.
APAPO ÌGBÉLÉWÒN
1 Ko faweeli àìránmúpè sílè
- Ko faweeli aàraánmuúpeè sílè
- Ko kónsónántì èdè Yorùbá sílè
- Ta ni oba ìlú Mékà nigba kan ri?
- Ki ni o fa ti Odùduwà fi gbera lati ìlú Mékà wa si ile Ife
- Ki ni a n pe ni lítírésò?
- Orisii l lítírésò mélòó ló wa?
- So ìwúlò lítírésò meta.
ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ
- Eko ede ati asa Yoruba. Iwe kin-ni-ni oju iwe 55-56 lati owo Egbe Akomolede ati asa Yoruba
- S Y Adewoyin New Simplified Yoruba for Junior Secondary School JSS 1 Copromutt Publishers oju iwe 75-76.
ISE ASETILEWA
- Faweeli aranmupe ni ……. (a) I (b) o (d) an
- Faweeli roboto ni ….. (a) I (b) o (d) e
- ….. je konsonanti ti o maa n da duro bi odidi silebu ti o si maa n gba ami sori (a) m/n (b) b (d) f
- …….. ni oba ilu Meka nigba kan ri (a) Buremo (b) Okanbi (d) Lamurudu (e) Oduduwa.
- Litireso atenudenu naa ni a mo si …… (a) abalaye (b) apileko (d) itan
APAKEJI
- Salaye idi ti Oduduwa se gbera lati ilu Meka wa si ile Ife.
- a. Kin ni itumo litireso ede Yoruba?
b. Ko iyato meta ti o wa laarin konsonanti ati faweeli ede Yoruba?