ORO ONISÍLÉBÙ KAN
ÒSÉ KEJÌ
ORO ONISÍLÉBÙ KAN
Bá Bé Bé Bí Bó Bó Bú
Dá Dé Dé Dí Dó Dó Dú
Gbá Gbé Gbé Gbí Gbó Gbó Gbú
Já Jé Jé Jí Jó Jó Jú
Má Mé Mé Mí Mó Mó Mú
Sá Sé Sé Sí Só Só Sú
Pá Pé Pé Pí Pó Pó Pú
ÌGBÉLÉWÒN
1 Pe àwon òrò wonyi
-
- Fá Fé Fé Fí Fó Fó Fú
- Gá Gé Gé Gí Gó Gó Gú
- Ká Ké Ké Kí Kó Kó Kú
2 [a] ko faweeli airanmupe sile
[b] ko faweeli aranmupe sile.
A Konsonanti:- Kónsónántì ni àwon ìró tí ìdíwó maa n wá fún èémí won nigba ti o n ti inú èdòfóró bò nígbà tí a ba n pè wón.
Gbogbo àwon ìró kónsónántì wonyi kì í gba àmì sórí àfi kónsónántì àránmúpè àsesílébù [n/m] bakan náà ni won kì í parí òrò Yorùbá. Won le bere oro Yorùbá bee a si le ri won laarin oro Yorùbá sugbon won ki i pari oro yoruba. Gbogbo kónsónántì èdè Yorùbá jé méjìdínlógún (18). Apeere awon konsonanti naa ni:
Bb Dd Ff Gg GBgb Hh Jj Kk Ll Mm Nn Pp Rr Ss Ss Tt Ww Yy.
Awon iro konsonanti ki i pari oro Yorùbá. Koda bi oro ohun ba je oro ayalo, a maa n fi faweli pari iru oro bee ninu ede Yoruba. Fun apeere:
Class ------ Kilaasi.
Bread ------ Buredi
Ko tan sibe, konsonanti ki i tele ara won ninu ede Yorùbá. Iyen ni wi pe a ki i ni isupo konsonanti ninu oro Yoruba. Apeere:
Otta ---------- Ota Oshodi ------- Osodi Shade -------- Sade
Ogbomosho --- Ogbomoso
Konsonanti ki i da duro bi iso kan ninu oro Yorùbá ayafi Konsonanti Aranmupe Asesilebu (m/n). Awon wonyi le da duro bi iso kan ki won si gba ami sori. Won maa n sise konsonaanti pelu ise faweli ninu gbolohun. Apeere:
Bamgbola Ba- m-gbo-la
Kongo Ko-n-go.
Ade n lo ile. Ade n lo Ile
B Fáweli:- Faweli ni àwon ìró tí èémí won kì í ní ìdíwó nígbà tí a bá n pè wón jade láti inú èdòfóró. Orisii méjì ni faweli pín sí. Àwon náà ni:
-
- Faweli Airanmupe: Aa Ee Ee Ii Oo Oo Uu (7)
- Faweli Aranmupe: an en in on un (5)
Iro faweli a maa gba ami sori ki o si da duro bi odindi silebu. Apeere:
O lo si ilu Ota. E wa ile Kunle ri i. Won pe e.
Alagbada. Bola gun keke. Aja pa eku.
Faweli ‘u’ ki ibere ede ajumolo, o le bere oro ninu eka-ede Ekiti ati Ijesa. Apeere:
Yoruba Ajumolo: isu ile igba
Ekiti/Ijesa: usu ule ugba.
APEJUWE IRO FAWELI
Gege bi a ti so saaju pe orisii iro faweli meji ni o wa ninu ede Yorùbá ati wi pe gbogbo awon iro faweli ohun je mejila ni apapo. Ki a ma gbagbe wi pe gbogbo iro faweli ni won je iro akunyun. Ni bayi a fe ye apejuwe awon iro faweli wonyi wo ni okookan. Ona merin ni a n gba se apejuwe iro faweli. Awon naa ni:
- Ipo Afase.
- Giga odidi ahon.
- Ipo Ete.
- Apa kan ara ahon to gbe soke
- Afase: je okan lara eya ara ifo/afipe ti a fi n pe iro jade. Enu ni afase yii wa, eran jobojobo ni. Afase yii le di ona ti o lo si kaa imu. Ni igba yii ni a maa n ni iro faweli airanmupe ( a, e, e, i, o, o o, u). Sugbon igba ti afase yii ba di kaa enu, eemi ko ni le gba enu jade ayafi kaa imu. Igba yii ni a maa n ni faweli aranmupe (an, en, in, un, on).
- Giga Odidi Ahon. Ayewon finnifinni fi ye wa pe bi a ba se la enu to ni ahon se maa n se wale si ti o sit un je wi pe bi a ba se pa enu de to ni ahon se maa n se ga to. Ahon le wa ni oke patapata, ebake, ebado ati odo. Ni ipo kookan yii ni a ti maa n pe orisii iro. Fun apeere ni igba ti ahon ba wa ni oke, a maa n pe faweli iro ‘i, in, u ati un’’ ti ahon ba wa ni ipo ebake ba wa ni ebake, a maa n pe ‘’e ati o’. ti ahon ba wa ni ipo ebado, a maa n pe ‘e, en, o, on’. Ni igba ti ahon ba wa ni ipo odo, a maa n pe iro faweli ‘a ati an’’
- Ipo Ete: Ona meji ni ete le wa. Ete le wa ni perese. Igba yii ni o maa n dabi igba ti efin siga jade lenu. Awon iro ti a maa n pe jade ni igba naa ni: i, e, e, in ati en. Ona keji ni roboto. Awon iro ti a maa n pe ni igba yii ni: u, o, o, un ati on. /u/, /o/, /ɔ/.
- Apa kan odidi ahon: ona meta ni a le pin isori yii si. Awon naa ni: iwaju, aarin ati eyin. Ti ahon ba gbe soke si iwaju, awon iro ti a maa n pe ni: iro faweli i, e, e /i/, /e/, / ɛ/. ti ahon bag be soke ti o si wa ni aarin, awon iro ti a maa n pe ni. Iro faweli: a ati a, an ( /a/, /a/ ).
Apejuwe iro faweli airanmupe. Afase maa n di kaa imu nigba ti a ba n pea won iro wonyi ni ni eemi fi maa n gba kaa enu jade pea won iro wonyi.
ATE FAWELI AIRANMUPE
/a/: faweli airanmupe odo, ayanupe, akunyun, aarin a se enu perese pe e.
/e/: faweli airanmupe ahanudiepe, akunyun ebake iwaju a se enu perese pe e.
/ɛ/: faweli airanmupe ayanudiepe akunyun ebado iwaju a se enu perese pe e.
/i/: faweli airanmupe ahanupe akunyun oke iwaju a se enu perese pe e.
/o/: faweli airanmupe ahanudiepe akunyun oke eyin a se enu roboto pe e.
/ɔ/: faweli airanmupe ayanudiepe akunyun ebado eyin a se enu roboto pe e.
/u/: faweli airanmupe ahanupe akunyun oke eyin roboto.
ATE FAWELI ARANMUPE
/a/: faweli aranmupe ayanupe akunyun odo aarin a se enu perese pe e.
/Ɛ/: faweli aranmupe ayanudiepe akunyun ebado iwaju a se enu perese pe e.
/i/ faweli aranmupe ahanupe akunyun oke iwaju a se enu perese pe e.
/Ɔ/: faweli aranmupe ayanudiepe akunyun ebado eyin a se enu perese pe e.
/u/: faweli aranmupe ahanupe akunyun oke eyin a se enu perese pe e.
IGBELEWON
- ……. ni iro ti eemi re maa n ni idiwo nigba ti a ba n pe e jade (a) konsonanti (b) faweli (d) iro (e) konsonanti ati faweli.
- Iro ti iro re ko ni idiwo ni iro ………… (a) faweli (b) konsonanti (d) iro (e) ami.
- ……. je okan pataki ti iyato fi wa laarin konsonati ati iro faweli. (a) konsonanti ki i pari oro Yoruba (b) ko si ibi ti faweli ko le duro si ninu oro Yoruba (d) faweli le bere oro Yoruba bee si ni konsonanti naa le bere oro Yoruba (e) odiwon konsonanti ati faweli jo ara.
- Faweli ti ko ki n bere oro ajumolo ni …….. (a) a (b) b (d) m (e) e.
- Iro ti ki i tele ara won ninu oro Yoruba ni …….. (a) faweli (b) konsonanti (d) ami (e) omi.
- Ewo ni o maa n gba ami sori ninu awon iro wonyi? (a) b (b) d (d) f (e) m/n.
- ……. je iro iwaju. (a) a (b) u (d) o (e) i
- Ewo ni o je faweli eyin ninu awon wonyi? (a) a (b) e (d) in (e) u.
- Faweli roboto ni ………. (a) a (b) in (d) un (e) an.
- Faweli aranmupe ni ……….. (a) an (b) I (d) o (e) e
- Ko iyato meta laarin iro konsonanti ati iro faweli sile.
- Ko apeere faweli airanmupe meje sile.
- Ko apeere faweli aranmupe marun-un sile.
Se apejuwe awon iro yii sile: a, e, in, u, on, i ati un.
ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ
S Y Adewoyin New simplified Yoruba L1 iwe kin-in-ni Copromutt Publishers oju iwe 1-2
ORÍ-ÒRÒ - ILE-IFE SAAJU DIDE ODUDUWA
- ÀWON TÓ BÀ PÀDÉ
- ILU TO TI PÀDÉ WON
- ÀJÓSEPÒ TÓ WÀ LÁÀRIN WON
ILÉ IFÈ SÁÁJÚ DÍDE ODÙDUWÀ
Gbogbo àwon ìlú tí Odùduwà àti àwon ènìyàn re la kojá ni won ti bá àwon ènìyàn pàde. Àwon ìlú bi Sudan, Òkè oya, Ile Boronu, Ile oba Sókótó. Gbogbo àwon ílú wonyi ni Odùduwà ti ba àwon ènìyàn pàde sùgbón kò fi bée sí ìbásepò to dan mórán láarin won, àwon tí kò le ba Odùduwà dé ile-ife nitori ààre tó mu won ni won tèdo si àwon ìlú wonyi títí di òní yìí. Èyí lo fa a to fi dabi pe èdè Yorùbá àti èdè àwon ìlú wonyi jo ara won die, bi a ba wo o dáadáa.
Nígbà tí wón dé Ilé-Ifè, Odùduwà ba Àgbonmìrègún, Baba-ifá àti àwon ènìyàn re pade. Bi àwon òpitàn se so, won ni Obàtàlá ni oba ilú Ife nígbà náà sùgbón enu re ko ká ìlú, àwon Ugbo si wá ko àwon ife lérú, won sì je gàba lé won lórí. Gbogbo ohun to n selè yìí kò te Odùduwà lórun, o dìtè mo Obàtàlá, o si lee kúrò lórí oyè. Ki àwon ara ìlú to soro pe ohun to se ko te won lorun, o ti kogun ba àwon Ugbo, ó sì ségun won èyí lo sì mu ki àwon Ilé-Ifè so di àyànfé, ti won si fi joba gégé bi Òòni Ilé-Ifè.
ÌGBÉLÉWÒN
1. Àwon wo ni Odùduwà bá pàdé nínú ìrìnàjò re?
2. Àwon ìlú wo lo ti pàdé àwon ènìyàn
b. Ibasepo wo lo wa láàrin Odùduwà àti àwon ènìyàn náà.
ÌGBÉLÉWÒN
1. Àwon wo ni Odùduwà bá pàdé nínú ìrìnàjò re?
2. Àwon ìlú wo lo ti pàdé àwon ènìyàn
3 Ibasepo wo lo wa láàrin Odùduwà àti àwon ènìyàn náà.
4 Faweli ede Yoruba je .......... ni apapo
5 Ko ofin meji ti o de konsonanti.
ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ
Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe kin-in-ni lati owo Egbe Akomolede Ati Asa Yoruba, Oju iwe 1-2
ISE ASETILEWA
- …….. je apeere faweeli aranmupe (a) a (b) o (d) in
- Gbogbo faweeli ede Yoruba je …….. ni apapo (a) ogun (b) mejidinlogun (d) mejila
- Ewo ni konsonanti ninu awon wonyi (a) a (b) in (d) m.
- …… je okan lara awon ti Oduduwa ba nile ife (a) Buremo (b) Oranmiyan (d) Obatala/Agbonmiregun.
- ……. Je litireso ti o ni akosile (a) apileko (b) atenudenu (d) atowoko
APA KEJI
- Àwon wo ni Odùduwà ba pade ninu irinajo re?
Àwon wo ni Odùduwà ba pade ni ile ife?
- ko orisii lítírésò ti a ni ninu èdè Yorùbá.