LETA AIGBEFE
OSE KEJI
LETA AIGBEFE
Akoonu:
- Leta aigbefe
- Igbese kiko leta aigbefe
Leta aigbefe je leta ti ko gbefe rara, ti a ko si eni ti o wa ni ipo giga tabi aaye owo. O le je leta iwase, leta ifisun, leta igbaaye lenu ise, leta si ijoba ibile. Igbese meje ni a ni lati tele bi a ba fe ko leta aigbefe. Awon naa ni:
- Kiko adireesi akoleta.
- Kiko deeti ( ojo, osu ati odun ti a ko leta).
- Ipo ati adireesi eni ti a n ko leta si.
- Ikini ibere leta.
- Akole leta.
- Koko oro inu leta.
- Ipari ati oruko akoleta.
Kiko adireesi akoleta: bakanaa ni eleyi ri pelu leta gbefe.
Kiko deeti: eleyi naa ko fi bee yato si ti leta gbefe. 22/3/2011., 22 Erena, 2011.
Ipo ati adireesi eni ti a ko leta si: eleyi se Pataki ninu leta aigbefe.
3, Opopona Olowu,
Ibudoko Adeyanka,
` Abule Egba,
Eko. 11-04-2011
Oludari,
Good Shepherd Schools
3, Opopona Olayinka,
Meiran.
Alagba A.B Oyeyemi,
Ikini Ibere: Apa owo osi leyi maa n wa bi i ti leta gbefe, sugbon oun ki i fi ipo ti akoleta wa si eni ti a ko leta si han. Apeere: Alagba, Oga, Madaamu, Olootu abbl.
Akole Leta: ibi yii ni akoleta ti maa n ko akole koko idi ti o fi ko leta gan-an. Apeere:
ITORO AAYE LATI MA WA SI ILE EKO
TABI
Itoro Aaye Lati Ma Wa Si Ile Eko
Koko Oro Inu Leta: gege bi a ti so pe leta aigbefe ni eyi. Ko si aaye awada ninu iru leta yii. Ibi koko leta ni a ni lati lo taara. Ki a ranti pe abala meta naa ni eyi pin si bi i ti leta gbefe: ifaara, aarin ati igunle.
Ipari ati Oruko Akoleta: ni ipari leta ni owo otun ni eyi maa n wa bi i ti leta gbefe sugbon awon oro ti a maa n ko yato si ti leta gbefe. Kotan sibe, akoleta maa n bu owo lu leta aigbefe leyin eyi ni yoo ko oruko re. Apeere:
Emi ni tiyin ni tooto,
Olasare Adegbagi.
Emi ni,
Kunle Osepotu.
IGBELEWON
- Ko adireesi ile yin sile pelu deeti
- Ko adireesi ijoba ibile re sile
- Ko leta lori akole yii. Ko leta si oga ile iwe re *lori idi ti o fi wa si ile iwe ni ana.*
IWE AKATIWA
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun oju iwe 185-190 University Press Plc.
ISE AGBE
Akoonu:
- Ise agbe
- Orisiirisii ise agbe
Lara ise isembaye ile Yoruba ni ise agbe. Ti ko ba si agbado ki ni a ba ma a pe ni eko yangan ni oro ise agbe nile Yoruba. O fere je wi pe ohun ni ise ti o wopo ju nile Yoruba ni aye atijo. Ise agbe ni awon ti o n se ipese ounje. Awon ni o n gbin (plant) nnkan bi ege, isu, anamo, mangoro, osan, ogede. Awon ni o sin (rear) ewure, maalu, aguntan elede. Ko tan sibe, won n se ipese awon ohun elo fun awon nnkan bi i baagi, bata, aso. Abbl. Orisiirisii ise agbe ti o wa ni:
- Agbe ologbin
- Agbe olosin
- Agbe alaroje
- Agbe aladanla
OHUN ELO AMUSEYENI: Apere, oko, ada, ahere, gberi, ohun ogbin: eebu isu, agbado, ewa/ere,osan/koro osan, koro ibepe
IGBELEWON
-
- Ki ni itumo ise agbe?
- Ko apeere ise agbe merin sile
APAPO IGBELEWON
- Ki ni itumo ise agbe?
- Ko apeere ise agbe meji sile
- Ko leta si ore re lori bi o ti fe lo isimi olojo gbooro ti o n bo yii
ATUNYEWO EKO
- Ko gbogbo iro konsonanti sile.
- Ko gbogbo iro faweli sile.
IWE AKATILEWA
Olu Daramola (1975) Awon Asa ati Orisa Ile Yoruba oju iwe 171-181.Onibon oje Press & Book Industries (Nig) Ltd.
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji University Press Plc oju iwe 207-214
ISE ASETILEWA
- …..ni leta ti a nko si oga ile-ise ni. (a) gbefe (b) aigbefe (d) alarojinle (e) onisorogbesi.
- Ibo ni adiresi akoleta maa n wa? (a) egbe osi leta (b) apa otun oke (d) apa osi loke (e) isale leta patapata.
- ……… ko si ninu igbese leta gbefe. (a) adireesi eni ti o n gba leta (b) ikini ibere (d) deeti (e) adireesi akoleta.
- Awon onise owo wo ni won maa n se ipese isu, ege,ewa. Awon agbe…… (a) ologbin (b) olosin (d) oloko nla (e) ounje.
- Lara irinse agbe ni …… (a) oko/ada (b) iwe (d) ina monamona (e) abo
APA KEJI
- Ko leta si oga ile-iwe re lori iwulo eko nipa ise agbe nile iwe.