Skip to content

We use essential cookies to sign you in and remember your settings. With your permission we also use analytics cookies to understand how the site is used. See our privacy policy or fine-tune this anytime at cookie settings.

SubjectFree lesson

LETA GBEFE

ClassNotes Team 4 MIN READUPDATED 7 JUL 2026

OSE KIN-IN-NI

LETA GBEFE

AKOONU:    Itumo

                    Adireesi

                    Deeti

                   Ikini ibere

                    Koko aroko

                    Asokagba

                    Ikini ipari

Leta kiko ni ona ti a n gba ranse asiri si ara eni. Oun ni o duro fun aroko pipa lode oni. A maa n fi ero ara eni han ninu iru leta (aroko) yii. Aroko onileta nise pelu kiko sile. Leta  yii pin si orisii meji awon naa ni: leta gbefe ati leta aigbefe. Leta gbefe ni leta si obi, ore, ibatan ati awon miiran ti o sun moni.

Igbese/Ilana Leta Gbefe

          Kiko  adireesi: oke apa otun ni a maa n ko adireesi eni ti o n ko leta si. Ninu  adireesi yii, a maa n ri nomba, adugbo,opopona, ipinle. Fun apeere:

                                                          3, Opopona Olowu,

Adugbo Bodija,

Ilu Ibadan.

 

                                                                                       3, Opopona Olowu,

                                                                                       Ibudoko Adeyanka,

                                                                                                 Abule Egba,

                                                                                       Eko.                                                                                                  11-04-2013.

          Kiko deeti: leyin ti a ba ko adireesi leta tan, a o ko deeti ojo, osu ati odun ti a ko  leta. Fun apeere: 22 : 3 : 2011. tabi 22 Erena, 2007.

          Ikini ibere: apa owo osi lori ila ti o tele deeti ni a maa n ko eyi si. Fun apeere:

Omo mi owon, Omo mi tooto, Iya mi atata, Ore mi owon, Egbon mi tooto, Tunji mi atata,.

          Koko aroko: nibi ni a ti maa n ko ohun ti o mu wa ko leta gan-an. Ona meta ni abala yii pin si. Awon naa ni: ifaara (introduction) aarin (body of the leta) igunle (conclusion). Ninu ifaara ni a ti maa ko idi ti a fi ko leta lerefe tabi ni soki, inu aarin leta ni ti maa n se alaye lekunrere fun eni ti a ko leta si nigba ti igunle maa je ibi ti a ti maa se igunle leta wa. Ni igba yii, a le ki eniyan nibe.

          Ipari ati oruko akoleta: apa owo osi ni isale ni eyi maa n wa. A ni lati fi sokan wi pe ipari iru leta yii ni ibuwolu ninu. Eyi je okan lara ohun ti o mu leta gbefe yato si leta aigbefe. App.

 

 

 

Emi ni omo yin,

Babatunde.

 

Baba re,

Adewuyi.

 

Ore re,

Folake.

IGBELWON

  1. ko adiresi ile iwe re sile.
  2. Se alaye perete lori koko oro leta.

IWE AKATILWA

Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun oju iwe 185-190 University Press Plc

 

AWON ISE ISEMBAYE ILE YORUBA

Akoonu:

  • Ise isembaye
  • Orisiirisii ise isembaye ile Yoruba

Awon Yoruba bo won ni, ki agbado to de ile aye nnkankan ni adiye n je. Opolopo eniyan lo gba wi pe awon baba nla wa nile Yoruba ko ni ise ti won n se ki awon eniyan alawo funfun to de. Iro patapata gbaa ni. Awon ise ti awon baba nla wa n se nile Yoruba ni a pe ni ise isembaye. Awon iru ise bee ni: 

  1. Ise ilu lilu
  2. Ise aso hihun
  3. Ise eni hihun
  4. Ise gbenagbena
  5. Ise awako
  6. Ise agbede
  7. Ise ode
  8. Ise oloola
  9. Ise agbe
  10. Ise pejapeja
  11. Ise awo kiko
  12. Ise ogun jija
  13. Omuwe
  14. Onidiri
  15. Amokoko

IGBELEWON

  1. Nje awon Yoruba ni ise bi ki awon alawo funfun to de?
  2. Daruko awon ise isembaye ile Yoruba meje.

OHUN ELO AMUSEYENI: Oko, Ada, Olu, Emu Agbede, Ikoko, Igbin, Abe, Duru Kongo, Igi Omi. Osun.

APAPO IGBELEWON

  1. Ko adireesi ile iwe re sile.
  2. ko adiresi ile iwe re sile.
  3. Se alaye perete lori koko oro leta.

IWE AKATILEWA

Olu Daramola (1975) Awon Asa ati Orisa Ile Yoruba oju iwe 171-181.Onibon oje Press & Book Industries (Nig) Ltd.

ATUNYEWO EKO

  1. Salaye itan isedale Yoruba.
  2. Ko oruko awon omo Okanbi mejeeje sile.

ISE ASETILEWA

  1. Leta…..ni leta ti a nko si baba, iya tabi eni ti o sunmoni. (a) gbefe (b) aigbefe (d) alarojinle (e) onisorogbesi.
  2. Ibo ni adiresi akoleta maa n wa nihin-in? (a) egbe osi leta (b) apa otun loke (d) apa osi loke (e) isale leta patapata.
  3. ……… ko si ninu igbese leta gbefe. (a) ori (b) ikini ibere (d) deeti (e) adireesi akoleta.
  4. Awon wo ni won maa n pe ni ayan? (a) onilu (b) agbe (d) awo (e) awako.
  5. Awon ti won maa n gbin nnkan ni …… (a) ode (b) agbe (d) onilu (e) gbenagbena

APA KEJI

  1. Ko awon ise isembaye ile Yoruba marun-un sile.
  2. Ko igbese leta gbefe marun-un sile.