EDE GBOLOHUN ONIBO
OSE KEJI
EDE GBOLOHUN ONIBO
AKOONU
- Oriki gbolohun onibo
- Apeere atoka/wuren gbolohun onibo
- Apeere gbolohun
Ni opo igba a maa n pe gbolohun onibo ni gbolohun olopo oro ise tabi gbolohun alakanpo.Gbolohun onibo ni eyi ti a fi gbolohun kan ha ihun omiiran. Irufe gboloun yii maa n ni ju eya kan lo. Atoka/wuren gbolohun onibo ni: ti, ki,iba,ni,pe,nigba,bi.Fun apeere.
O gba ile ti mo ra
E gbodo so fun mi ki e to wa
A o jo lo bi e ba de
Iba se pe mo lowo, n ba ra moto
Kani e tete de ni,e ba ba won
Gbogbo ilu gbo pe oba waja
IGBELEWON
Fa ila si idi gbolohun onibo nihin
- O dara pe mo ra iwe
- A gbodo lo bi ojo baro
- Ibaje je pe mo lowo n ba kole
- Awon obinrin ti o mo
- Omobinrin yen le pada bi o ba fe
IWE AKATILEWA
AyoBamgbose (1990) Fonoloji ati Girama Yoruba University Press Ltd oju iwe 192-200
ETO IGBEYAWO ABINIBI
AKOONU
- IFOJUSODE
- ALARINA
- IJOHEN/ISIHUN
- ITOORO
- IDANA
ASA IGBEYAWO ATIJO (IBILE)
IGBESE IGBEYAWO ALAYE
Ifojusode Awon obi okunrin yoo maa fi oju sile wa obinrin.
Iwadii Won yoo se iwadii idile obinrin naa ni aarin ilu. Won yoo tun se,
Iwadi lowo ifa.
Alarina Alarina ni won yoo maa rann si ara won( oko ati Iyawo afesona), Boko
ba moju aya
Tan, alarina a yeba.
Isihun/ijohen Gbigba ti obinrin gba lati fe okunrin.
Itoro Awon ebi okunrin yoo wa toro omobinrin ni owo obi re.
Baba gbo, iya Awon ebi mejeeji gbo, won si gba pe ki obinrin ati okunrin feragbo
Idana Ebi oko yoo gbe eru idana lo fun ebi omobinrin ti ojo igbeyawo won
Ba ku feere.Isu ogoji, orogbo ogoji, obi ogoji.
Ifa iyawo Baba iyawo yoo difa ni aaro ojo igbeyawo lati mo ile oko naa yoo se
Ri boya yoo san sowo somo.
Ojo igbeyawo Ale ni awon ebi ati ore iyawo yoo ba a palemo, won yoo sin iyawo lo
Si ile oko pelu orin ati ijo titi yoo fi de enu ona oko re.
Ese iyawo Ni enu ona abawole won yoo fi omi we ese iyawo naa.
wiwe
Ibale Ti iyawo ko ba ti i mo okunrin kan ri, ti oko re ba a nile, oko yoo gbe
ekun agbe emu tabi ile isana kikun ranse si obi iyawo pelu owo ibale.
IGBELEWON
1. Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi
2. Se alaye ise alarena
3. Kini ijohen tabi isihun tumo si?
4. Kini iyato laarin itoro ati idana?
IWE AKATILEWA
1. Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji Longman Nig oju iwe114-118
2. Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun (J S S 2) iwe keji University Presss oju iwe 85 92
ISE ASETILEWA
1 Gbolohun ti a fi ihun re ha omiiran ni golohun…. (a) ase (b) onibo (d) afibo
2 Ki je atoka gbolohun ……(a) olori (b) onibo (d) afibo.
3. Awon wo lo maa n se itoro omo? (a) idile iyawo (b) idile oko (d) idile iyawo ati oko
4. Ise alarina ni lati maa ..........(a)se oju fun iyawo lodo baba oko (b) se atunse laarin oko ati iyawo (d) Soju oko lodo baba iyawo
5. Gbogbo ohun ti a n san lori iyawo ti a fe fe ni a n pe ni ........... (a) Owo igbeyawo
(b) Owo ijohen (d) owo ori
APA KEJI
1. Kini a n pe ni idana ninu eto igbeyawo nile Yoruba
2. Kini ijohen, lati odo tani ijohen ti n wa?
3 Toka si gbolohun onibo nihin-in
- Gbogbo ilu gbo pe oba waja
- Bade ka iwe ki o le yege
- N o ni lo kani mo mo
- Mo ti lo ki ore mi to de
- Akekoo naa mura ki o le gbebun