ORI ISE: Atunyewo fonoloji ede Yoruba
OSE KIN-IN-NI
ORI ISE: Atunyewo fonoloji ede Yoruba
AKOONU:
- Iro konsonanti
- Iro faweeli
- Iro ohun
Fonoloji tumo si eto bi a se n sin awon iro kookan po di oro ninu ede Yoruba. Awon iro to se pataki ninu ede Yoruba ni iro faweeli, iro konsonanti ati iro ami ohun.
- IRO FAWELI
Ona meji ni a pin iro faweli si, awon ni faweeli aranmupe ati airanmupe.
Faweeli Airanmupe ni:
AKOTO FONETIKI
a a
e e
e
i i
o o
o ↄ
u u
Faweli aranmupe:-
Akoto Fonetiiki
an a
e ԑ
i i
o ↄ
u u
Bi a ba fe se apejuwe iro faweli, a ni lati kiyesi ipo ti ahon wa ninu enu, boya a ranmu tabi a ko ranmu pe e, bi ete se ri lasiko ti a pe e ati bi ahon se lo si iwaju tabi seyin.
- IRO KONSONANTI
Iro miiran to tun se koko ninu èdè Yoruba ni iro konsonanti. Mejidinlogun (18) ni iro konsonanti, Awon ni:-
AKOTO b d f g gb h j k l m n p r s s t w y
FONETIKI bd f g gb h dz k l m n kp r s s t w y
Bi a ba fe se apejuwe awon iro konsonnati, a gbodo kiyesi boya iro akunyun tabi iro aikunyun ni. Ninu akoto ode oni konsonanti meji ko le da duro tabi ko tele ara won ninu oro.
- IRO OHUN
Orisii iro ohun keta ti a ni ninu ede Yoruba ni iro ohun. Iro ohun ni o maa n se iyato laarin oro ti won ba ni faweli ati iro konsonanti kan naa. Awon iro ohun ti a ni niwonyi:-
Iro ohun oke ( / )
Iro ohun aarin ( - )
Iro ohun isale ( \ )
Awon iro meteeta to se Pataki yii ni a n pe ni foniimu. FonIiro aseyato ninu oro. Apeere:-
Aja
Aja
Aja
Ori iro faweli ati konsonanti “n ati m” nikan ni a maa n fi ami ohun le lori.
IRO KONSONANTI ATI FAWELI
Ada aja apa ara ala agba aba aya
Ede ade epe ere ele egbe ebe aye
Ese epe ete efe eye eke ere ede
Idi iti iyi iri igi ika ide ire
Odo oyun oku okun osun ori osi ose
Omo oko oto opo oso ofe ope oke
PE AWON ORO YII
Adaba oginlinti ajapa alade alakori oronbo
Iwonyi ofin amebo akunyun aikunyun
Konkoso pongila sogigun sakatapara aganrandi
Irere alabahun tafatafa jagunjagun atamatase
Iwerende tonbolo okodoro gbagede aamebo.
IGBELEWON
- Ki ni a n pe ni fonoloji?
- Awon iro meta wo lo se Pataki ninu ede Yoruba?
- Ona meloo ni a pin iro faweeli si?
- Orisii ami ohun meloo ni a ni ninu ede Yoruba?
- Ki ni a n pe ni foniimu?
IWE AKATILEWA
- S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 (JS1) Copromutt Pubisher Oju iwe 50-53
2. Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji University
Press Ltd Oju iwe 1-6
ATUNYEWO ASA
AKOONU:
- KINI A N PE NI ASA
- ORISIIRISII ASA YORUBA
Nigba ti a ba menu ba asa awon eniyan kan, ohun ti a ni lokan ni iwa ati isesi awon eniyan naa. Ki i se iwa enikan soso ni a n toka si gege bi asa awon eniyan naa bi ko se iwa ajumohu. Iwa ajumohu le je mo bi won se n wo aso, ise ti won se, ounje ti won n je, esin won, iwa omoluabi, isinku ati oge sise. Ede je okan pataki ninu asa awon eniyan bee.
Ki i se awon nnkan wonyii nikan ni a le pe ni asa won. Bakan naa ni a le pe eewo, eto oselu ati owe ti awon eniyan naa maa n pa si asa won.
Orisirisi asa ni a ni ni ile Yoruba to n fi iwa ati isesi awa Yoruba han awon asa yii po lo sua bi ola Olorun. Ni opo igba ni awon agbalagba maa n so pe awon omode n ko asakasa. Eyi nipe iru awon omo bee n huwa ti ko ba ti awon eniyan re mu, iyen ni pe asa ti ko ba je teni ti ko ba iwa awon eniyan mu ni won n pe ni asakasa. Eyi ni pe asa ti ko dara.
Ni kukuru iwa ati isesi awa Yoruba ni a n pe ni asa Yoruba. Orisirisi asa ni a ni ni ile Yoruba, die lara won ni
- Asa igbeyawo
- Isomoloruko
- Isile
- Oye jije
- Isinku
- Ila kiko
- Aso wiwo
- Eto oselu
- Eewo kika
- Ogun jija
- Asa ikini
- Oge sise
ASA IKINI
Asa ikini je okan pataki ti a fi maa n da eya Yoruba mo laarin gbogbo eya ti o ku. Lati kekere ni imole ti n ko omo re laso, bee gege ni oro asa ikini je laarin awon Yoruba. Lati kekere ni won ti n ko omo ni orisiirisii ona ti a n gba ki ni nile Yoruba. Gbogbo akoko ni o ni bi a se n ki ni nile Yoruba. Ko si igba ti e ki i ki eniyan yala aaro, osan tabi ale koda a maa n ki eni ti o n sun lowo (asunji). Bee ni a ni orisii ikini fun igba kookan ninu odun bi igba ojo, oye, otutu, oginlintin. abbl.
Nile Yoruba, omokunrin maa n dobale ki eniyan ni ngba ti omobinrin maa n fi orunkun mejeeji kunle lati ki eniyan.
OGE SISE
‘ B’afinju w’oja, won a rin gbendeke, obun w’oja pa siosio’ ... aajo ewa ni oge sise je. Awon Yoruba je eya ti o faari pupo, won a maa wo aso to ba ara won mu. Ti o sit un ba ohun ti won n se lowo mu. Won a maa se itoju ara won lopolopo beeni won ki i fi itoju ayika won fale rara. A le so pe ma rin doti ni awon Yoruba. O je asa won ati ise won ni gbogbo igba lati tun ara ati ayoka won se ni ona ti yoo fi se e ri. Awon Yoruba ko fi owo yepere mu oge sise.
Die lara awon ona ti a n gba se oge nile Yoruba ni: itoju ara: iwe wiwe, enu fifo, tiroo lile abbl. Itoju ayika: ile gbigba, oko riro, fifo gota abbl
IGBELEWON
1. Ki ni a n pe ni asa?
2. Ko asa Yoruba marun-un sile.
IWE AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2015) Eko Ede Yoruba Titun iwe kin-in-ni University Press Ibd. oju iwe 153-178
AKORI ISE:ATUNYEWO EWI ALOHUN
AKOONU
- Eya litireso atenudenu
- Awon ewi to je mo ayeye
- Awon ewi to je mo esin
Eka meta pataki ni litireso atenudenu pin si. Awon eka meta naa ni ere onise, ewi ati oloro geere. Awon eya ewi alohun po to bee ti a ko le ka won tan. Gbogbo awon eya Yoruba lo ni orisirisii ewi atenudenu ni agbegbe won, sugbon awon kan wa to je pe gbogbo eya Yoruba lo n lo won. Die lara won ni ofo, rara, ijala, ekun-iyawo, iyere, ifa, oriki ati bee bee lo. Awon miiran wa to je pe adugbo kan ni a ti maa n ba won pade apeere bee ni olele, orin etiyeri, efe,bolojo, dadakuada ati bee bee lo.
Awon ewi alohun to je mo ayeye ni:-
- Ekun-iyawo
- Dadakuada
- Obitun
- Oku pipe
- Efe
- Ege
- Orin apepe ati bee bee lo.
Awon ewi alohun to je mo esin abalaye ni:
- Esu pipe
- Oya pipe
- Ijala.
- Orin oro
- Iwi eegun ati bee bee lo.
IGBELEWON
1. Daruko litireso atenudenu merin
2. So meta ninu ewi to je mo ayeye
3. Daruko meji ninu ewi to je mo esin
IWE AKATILEWA
- Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe Kin-in-ni. Longman Publisher O ju iwe 64-65
- S.Y Adewoyin (2003) New Simplified Yoruba L1 Book 1 Copromutt Publisher Oju Iwe 75-76
ASETILEWA
- …. ni iro aseyato (a) foniimu (b) iro (d) faweeli.
- A pin faweeli si faweeli airanmupe ati faweeli …… (a) iro ohun (b) aseyato (d) aranmupe
- Ami ohun ti a ni ninu ede Yoruba ni ami ohun oke, isale ati … (a) egbe (b) ikoko (d) aarin
- Ewo ni ki i se asa Yoruba nihin-in? (a) igbeyawo (b) isomoloruko (d) isile (e) ariwo pipa
- Ewo ni ki i se ewi atenudenu ayeye nihin-in? (a) rara (b) iyere (d) orin etiyeri.
APA KEJI
1 Ko apeere ewi alohun/atenudenu esin abalaye marun un sile.
2 Se alaye die lori asa ikini ati asa oge sise nile Yoruba.