AKORI ISE (EDE): IRO PIPAJE
OSE KIN-IN-NI
AKORI ISE (EDE): IRO PIPAJE
AKOONU:- Iro pipaje
Konsonanti pipaje
Faweeli pipaje
Iro pipaje ni dindin iye iro ti a pe ku nigba ti a ba n soro. A le pa iro konsonanti je be e naa ni a le pa iro faweeli je. Iro knosonanti pipaje ni dindin iye iro knosonanti ku nigba ti a ba n soro nigba ti iro faweeli pipaje maa je dindin iye iro faweeli ku ti a ba n soro. Iro pipaje yii wopo ninu eka ede Oyo. Awon iro ti a sakiyesi pe won saba maa n paje ju ni: r, w,y,’h,l ati k.
Apeere iro “r”
Akara – Akaa
Dire – Die
Apeere iro “w”
Jowo – Joo
Omoluwabi – Omoluabi
Apeere iro “y”
Adiye – Adie
Riyeriye – Rierie
Apeere iro “h”
Osugbohun – Osugboun
Olohun – Oloun
Apeere iro “l”
Metalelogbon – Metaleogbon
Tile – Tie
Apeere iro “k”
Adekiitan – Adeitan
FAWEELI PIPAJE:
Ibaluwe – baluwe
Iyanrin – yanrin
Omotola – Motola
Ka iwe – kawe
Eti Odo – Etido
Irun agbon – Irungbon
Ewe Oko – eweko
A o ri wi pe bi o tile je pe a pa iro knosonanti ati awon iro faweeli won yii je, ko se akoba fun itumo okankan ninu won.
IGBELEWON
- Kni ni iro pipaje?
- Se ipaje awon oro won yii, (i) ibaluwe (ii) Adiye (iii) Akara (iv) iyara (v) jowo (vi) Olohun
(vii) ewe oko (viii) Dire
IWE AKATILEWA
1 Eko ede ati asa Yoruba iwe keji oju iwe 78 – 81. iati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba
AKORI: ASA ISINKU ATI EWI ATENUDENU TO JE MO AYEYE ISINKU
AKOONU:-
- ASA OKU SISIN
- EWI TI A N LO NIBI AYEYE ISINKU
- IREMOJE, OKU PIPE ATI IGBALA SINSIN
Awon Yoruba gba pe bi aye ba ti ye ni si, ni sisin oku eni ni ti n rii. Bi olowo ba ku, bi won yoo ti sin oku re yato gedegbe si bi won se n sin oku mekunnu. Iru iku to ba pa eniyan ni yoo se okunfa iru isinku ti won yoo se. Bi omode ba ku, oku ofo ni, iwonba ni a le se lori oku bee. Bi ijoye ba ku, oku gbogbo ilu ni, be ni bi otosi ba ku, kii fi be mile rara.
Leyin ti oku ba ti ku, itufo ni o kan ti won ba ti tufo re ni won n gbe ile oku. Laye atijo inu ile ni won maa n sin oku si. Oku wiwe, lohun to kan. Awon Yoruba gba pe eni won to ku ko ku gbe ati pe bi won ba sin-in pelu idoti, inu idoti ni yoo wa laelae, eyi lo mu ki won maa we foku. Leyin ti won ba we fun tan ni won yoo dii pelu aso olowo iyebiye bi o tile je pe aso funfun ni won saba maa n lo. Laye atijo ti won ba n gbe oku lo si ibi ti won fe sin-in si, akobi oku lo maa saaju ti yoo si maa tu adiye irana rin.
Gege bi ewi atenudenu se wa fun ayeye igbeyawo ati ikomojade naa lo wa fun ayeye isinku agba. Lara awon ewi alohun ti a ya soto fun isinku ni oku-pipe, iremoje ati igbala sinsin. Yato si eyi orisi orin tun wa bakan naa ti awon eniyan maa n ko nigba ti oku ba ku, won a tun maa sun rara, akorin etiyeri ati pe won a tun maa da ege nibi oku agbalagba.
OKU PIPE: Yoruba ka iku si ohun ibanuje pupo. Nigba ti iku ba de, ekun a gba ile kan. Awon eniyan yoo bere si ni pohun rere ekun, won yoo si maa so orisirisi ohun to ba bo si won lenu lati fi edun okan won han. Iru ekun bayii ti won fi maa n pe oku bi eni pe ko dide soro ni a n pe ni oku-pipe.
IGBALA SISUN: Ewi ti awon eniyan fi maa n daro eni to ku nile Egba ni a n pe ni igbala sinsin. Ohun aro gba a ni won fi maa n sin-in ti ori awon ebi oku a maa wu pupo, o si maa n mu eniyan lokan gan-an.
IREMOJE Ale patapata titi di oganjo oru ni won maa n sun iremoje, ko dabi ijala ti won le sun nigba kugba. Ohun ti won fi n sun ijala naa ni won fi n sun iremoje. Awon ologun-un ati awon ode ni o maa n sun iremoje, ibi ayeye isinku akikanju ode ni o si ti maa n waye nitori orin idaro fun asekagba oku ode ni.
IGBELEWON
- Salaye soki lori awon ewi wonyi
(a) Oku-pipe (b) iremoje (d) igbala-sisun
2. Salaye bi a se n se eto isinku ni ile Yoruba
3. Awon ewi alohun wo ni a le lo nibi ayeye isinku
AKORI ISE (LIT): AWON EWI ALOHUN TO JE MO ESIN ABALAYE
Akoonu :-
- Iyere Ifa
- Esa egungun / Iwi
- Sango pipe
Ni aye atijo ki awon alawo funfun to mu awon esin igbalode wa saarin awon Yoruba, Orisirisi esin ni awon baba nla wa n sin ti awa si jogun ba lowo won. Bi orisii awon esin yii se wa naa ni a ni awon ewi alohun tabi ewi atenudenu ti a n lo fun okookan won. Iyen ni pe oni irufe ewi ti a fi maa n ki awon orisa kookan ti a n sin ni ile Yoruba.
Iyere ifa: ni orin awon babalawo ti won saba maa n ko ni asiko ti won ba n se odun ifa, sugbon iyere sisun le waye nigba ti babalawo ba n ki ifa lowo tabi ti won ba n se ayeye kan bii etutu ati igba ti won ba fe bo ifa.
Esa egungun/iwi: ni ewi alohun ti awon olusin egungun maa n lo nigba ti won ba n se odun egungun. Awon lo maa n je oruko mo oje, awon oruko bii Ojekunle Ojeniyi Ojedele ati bee bee lo. TakoTabo idile oloje lo le pe esa.
Sango pipe: ni ewi awon adosu sango awon ni olusin sango, o le je okunrin tabi obinrin, ko si eni ti ko le ki oriki sango. Asiko ti won ba n bo sango tabi se odun sango ni sango pipe ti maa n waye ju.
IGBELEWON
- Daruko ewi atenudenu merin to je mo esin abalaye pelu awon orisa ti won n fi awon ewi naa bo
IWE AKATILEWA
- Eko ede ati asa Yoruba iwe keta lati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba oju iwe 14 – 16.
ISE ASETILEWA
- Jowo yoo di ________ ninu ipaje/isunki (a) Jaa (b) Joo (d) Jowoo
- Ewo ni a ko le lo nibi ayeye isinku (a) Oku pipe (b) Igbala sisun (d) ekun iyawo.
- ________ ni o maa n tu adie irana (a) akobi oku (b)abigbeyin oku (d) egbon oku
- Esa egungun ni a mo si _________ (a) iwi kike (b) owe kike (d) iwi siso
- ________ ni won n fi iyere sisun bo (a) Ifa (b) Esu (d) Babalawo
APA KEJI
- Awon ewi alohun wo ni a le ba nibi isinku.
- Ko ewi alohunmarun ti a le ba nibi esin abalaye sile.
- Se isunki/ipaje awon oro wonyi
- Jowo
- Omolara
- Omoluabi
- Adiye