AROKO ALALAYE
OSE KEJI
AROKO ALALAYE
AKOONU: Aroko Alalaye
Ilapa ero
Aroko alalaye ni a fi n se ekunrere alaye lori ori-oro kan ti eni ti o ba ka aroko bee kofi ni ni isoro lati mo ohun ti alaye wa da le lori.Apeere ori oro aroko alalaye ni :
Ise ti mo fe se lojo iwaju
Igba erun
Eba tite
Ise tisa
Eran osin
ILAPA ERO ( Ise ti mo fe se lojo iwaju}
Iru ise wo ni o fe lojo iwaju
Alaye lekun-un rere lori ise naa
Idi ti ise naa fi wu o
Iru ipo wo ni ise yii le gbe o de
Ero re lori ise yii.
IGBELEWON
- Kin-in-ni aroko alalaye?
- Ko ori meta ti aroko alalaye
- Ko ilapa ero lori Igba erun
- Ko aroko lori eba tite
IWE AKATILEWA
1 New simplified Yoruba L1 iwe keta oju iwe 80-83 lati owo S Y Adewoyin.
AKORI ISE (ASA): OGUN PINPIN
AKOONU: Ogun pinpin
Ilana ogun pinpin.
Ohun ti a le pin gege bi ogun
Ona ti a n gba pin ogun.
Leyin osu meta ti okunrin ba ku ni a to le pin ogun re, leyin ti obinrin ba jade opo. Nile Yoruba, egbon ki I jogun aburo afi ti koba si elomiran mo sugbon apeere ori buruku ni ki egbon o jogun aburo re.
Ki won to pin ogun, won yoo difa tabi ki won pe awon agbagba lati jiroro laarin awon omo oku. Iru ipade bayi je ipade asiri. Won a kiyesi ohun ti awon omo naa fe ati ohun ti o le te oku lorun. Aaro kutukutu ni a maa n jokoo ni odede bale lati se eto ogun pinpin. Awon nnkan ti a n pin ni ogun ni: Aso, owo, ohun eso, ohun osin, orisa re, oko, iyawo ati gbese.
Ona meji ni a n gba pin ogun ni ile Yoruba awon naa ni: ori – ko – ju – ori ati idi – igi – si – idigi. Ori ko – ju ori – ni pinpin ogun si iye omo oku sugbon idi si idi igi ni pinpin ogun si iye iyawo ti o bimo fun oko naa.
IGBELEWON
- Ko awon nnkan marun – un ti a le pin gege bi ogun nile Yoruba.
- Awon ona wo ni a le gba pin ogun?
IWE AKATILEWA
- Eko ede Yoruba titun SSS iwe keji oju iwe 76 – 79. Lati owo Oyebamiji Mustapha.
ORI ORO:- Awon ewi atenudenu to je mo esin abalaye.
AKOONU:-
_ Ijala
_ Iwi/Esa
_ Oya pipe
IJALA:- Sisun naa ni won maa n sun ijala, orisa ogun si ni won fi n bo.
Awon olusin ogun ni awon ode, agbe, awon alagbede ati gbogbo awon to n sise irin. Ti won ba n se odun ogun ni ijala sisun saba maa n waye. Ounje ti ogun feran ni aja, iyan, obi, esun isu ati emu. Ogun korira gbigbe ofifo agbe emu duro.
IWI/ESA;-Awon idile eleegun tabi Oje ni won maa n ki iwi tabi pe esa egungun ni akoko ti won ba n sodun egungun. Ounje egungun ni emu, Olele, obi ati agbo. Eewo ni, egungun ko gbodo subu..
OYA PIPE:- Orisa oya ni won maa n fi oya pipe bo. Pipe ni won maa n pee ni akoko odun oya. Awon olusin re ni won n pe ni oloya sugbon awon obinrin lo maa n po ju ninu won nitori oya je orisa obinrin.
IGBELEWON:-
1. Daruko meta ninu awon ewi atenudenu to je mo esin abalaye.
2 Di awon alafo wonyi
EWI ESIN AWON TO N KEE
Sango pipe sango …………………..
Oya pipe ……………. ………………….
…………….. egungun …………………….
-
- Igba wo ni won maa n sun iyere ifa?
IWE AKATILEWA
1. Eko ede Yoruba titun iwe keji. Oju iwe 10-16 lati owo Oyebamiji Mustapha:
2. New simplified Yoruba L1 by S.Y Adewoyin book three. Oju iwe 17-19
3. . Eko ede ati asa Yoruba iwe keji. Oju iwe 14-18 lati owo Egbe akomolede ati asa Yoruba
ISE ASETILEWA
-
- Ohun ti a gbodo koko se ti a ba fe ko aroko ni ………..(a) yiyan ori oro (b) sise ilapa ero (d) sise ifaara
- Ewo lo yato ninu awon wonyi (a) alalaaye (b) apejuwe (d) itakuroso
- Ona melo ni awon Yoruba maa n gba pin ogun (a) meji (b) meta (d) merin
- Ohun ini ti oku fi sile ki o to ku ni won pe ni ………. (a) eru (b) dukia (d) ogun
- Iwi ni won maa n lo nibi esin ………… (a) oya (b) ogun (d) egungun
APA KEJI
- Ko ona ti awon Yoruba n gba pin ogun pelu alaye perete.
- Ko ewi alohun meta sile pelu ibi esin ti a ti maa n lo won.