Skip to content

We use essential cookies to sign you in and remember your settings. With your permission we also use analytics cookies to understand how the site is used. See our privacy policy or fine-tune this anytime at cookie settings.

SubjectFree lesson

ORO- ORUKO.

ClassNotes Team 8 MIN READUPDATED 1 JUL 2026

OSE KINNI

ORO- ORUKO

        - oriki

- orisiirisii oro oruko.

- ise ti oro oruko n se ninu gbolohun.

- lilo oro oruko ninu gbolohun.

          Oro –oruko ni awon oro ti won le da duro nipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun. AP.

          Baba ko ebe.

          Tolu fo aso.

          Mama se isu ewura.

EYA ORO ORUKO.

    1. ORUKO ENIYAN : -Oro oruko le je oruko eniyan, eyi ni oruko ti o n toka si ohun ti o je eniyan. Ap

-Rotimi

                   - Dele

                   -Ahmed

                   - Dokita

                   - Iyalaje…abbl

 2. ORO-ORUKO ALAISEEYAN:- Eyi ni oruko to  n toka si awon nnkan ti kii se eniyan AP. okuta, iwe, ewure, omi, iyanrin, bata abbl.

3.  Oro-oruko le je ohun elemi : - Eyi je oruko nnkan ti won ni emi bii eniyan tabi eranko.apaja,eniyan,esin,maalu,alangba,okunrin.abbl.

4.  Oro-oruko le je ohun alailemii: - Eyi ni awon nkan ti ko ni emi. ap iwe, ile, bata, ewe, igi: abbl.

5.  Oro-oruko le je ohun aridimu:- Eyi ni awon ohun ti a le fi oju ri tabi fi owo kan. apewa, eja,isu, tabili, sokoto, aga, ewedu, abbl.

6. Oro-oruko le je oruko ibikan :- Eyi ni awon oro oruko ti a le fi ibo se ibeere won. Ap ibo lo n lo? Osodi, Meka, Soosi.

7.  Oro-oruko le je ohun afoyemo:- Eyi ni awon ohun ti a ko le fojuri sugbon ti a le mo nipa ero opolo. Ap ogbon, ilera, ero, ife, alaafia, igbadun, wahala, imo.

8.  Oro-oruko le je aseeka : - Eyi ni o n toka si ohun ti a le ka Ap. Ile, ilu, eniyan, iwe, tatapupu.

9.  Oro-oruko le je alaiseeka : - Eyi ni o n tokasi awon ohun ti koseeka  Ap Iyanrin, epo, omi, afefe, gaari, irun.

10. Oro-oruko le je oruko igba:- Eyi ni oro ti a le lo lati toka si igba ti nnkan sele han. Ap Aaro, ana, odun, irole, oni, ola, ijeta

 

ISE TI ORO-ORUKO N SE NINU GBOLOHUN.

Ona meta pataki ni a le gba lo oro-oruko ninu gbolohun, o le sise:

i.Oluwa,

ii. abo

iii. eyan.

 

OLUWA: ni eni tabi ohun ti o se nnkan ninu gbolohun.

                 Baba ko ebe.

              Bola fo aso.

 

ABO:ni eni tabi ohun ti a se nnkan si, ap

                Mama se obe

             Bolu ko leta.

 

EYAN; ni o maa n se afikun itunmo fun oro-oruko ap

              Mama se eja yiyan.

              Bola ka iwe mewaa.

          Daruko orisii ere idaraya merin ti o mo.

 

IWE AKATILEWA

 Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 137-141.

 

ASA

ORISII ORUKO TI A LE SO OMO NILE YORUBA

Akoonu

Oruko se Pataki ni ile Yoruba, awon Yoruba kii sii deede fun omo ni oruko, awon oruko Yoruba maa n ni itumo. Idi niyi ti awon agba fi maa n se akiyesi ipo ti omo ba gba waye, Ipo ti ebi wa, esin idile baba ki won to fun omo ni oruko, Yoruba ni ile laawo ki a to so omo ni oruko.

Eyi ni orisii oruko ti a ni ni ile Yoruba.

Oruko amutorunwa

ii. Oruko abiku

iii. Oruko Inagije

iv. Oruko abiso

Oruko amutorunwa:- ni oruko ti a fun omo nipa sise akiyesi ona ara ti o gba wa si aye tabi isesi re nigba ti a bii. Apeere:

 

Oruko amutorunwa:-

Ige                                  Omo ti o mu ese waye

Aina                                Omobinrin ti o gbe ibi korun.

Ojo                                 Omokunrin ti o gbe ibi korun.

Oke                                 Omo ti o di ara re sinu apo ibi wa si aye epo tutu ni won maa

n ta si ara apo naa, ki o to le tu.

Oke                                 Omo ti o maa n daku ti won ba n fun ni ounje ni idubule.

Dada                               Omo ti irun ori re ta koko.

Ilori                                 Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi loyun

Oni                                  Omo ti won bi sile to n kigbe laisinmi

Babarinsa                         Omo ti baba re ku ni kete ti won bii.

Abiona                                     

 

Oruko abiku: Oruko ti a fun  omo ti o maa n ku, ti a sit un pada wa saye.

Won maa n fun won ni oruko bii ebe tabi epe ki won le duro.ap

Oruko                              Itumo

Durojaye       -        Ki o duro ni ile aye je igbadun

Rotimi          -        Duro ti mi, ma se fi mi sile.

Malomo        -        Duro si aye, ma pada si orun mo

Kosoko         -        Ko si oko ti a o fi sin oku re mo

Kasimaawoo  -        Ki a si maa wo boya yoo tun ku tabi ye.

Bamitale       -        Duro ti mi di ojo ale

Aja               -        Iwo ko ye ni eni ti a le fun ni oruko eniyan mo afi aja.

 

Oruko Inagije:- oruko atowoda ti a fi eniyan tabi ti eeyan fun ara re lati fi se aponle tabi apejuwe irisi tabi iwa re ap.

Eyinafe:        Eni tie yin re funfun ti o si gbafe.

Ajisafe:         Eni to feran afe ni owuro ti gbogbo eeyan ba n sise

Peleyeju:      Eni to ko ila pele, ti ila oju naa si ye e gan-an.

Oginni:         Eni ti o maa n roar n tele ginniginni.

 

Oruko abiso: eyi ni awon oruko ti o n tokasi ipo idile tabi obi omo saaju tabi asiko ti a bii.

Apeere oruko to n tokasi ipo tabi esin idile.

 

Ipo                                          Oruko abiso

Oba                                          Adebisi, Adegorite, Adegoroye, Adesoji, Adegbite, Adeyefa.

Eleegun                                     Ojewunmi, Ojeniyi, Eegunjo bi

Jagunjagun                                Akintola, Akinkunmi, Akindele

Onisona                                     Onajide, Olonade

Elesin Ifa                                   Fayemi, Faleye, Awobiyi, Awotunde

Onisango                                   Sangobunmi, Sangodele

Orisa Oko/Idobatala                    Efunjoke, Opakunle, Soyinka.

Orisa Ogun                                Ogunyemi, Ogunbiyi, Odetola.

 

Oruko to n toka si ipo obi saaju tabi ni akoko ti won bii.

Oruko                                                         Itumo

Ekundayo                                            Ibanuje ati ekun ti o wa ninu ebi di ayo.

 

Olabode                                              Ola to ti lo ninu ebi tun ti pada de.

Tokunbo                                             Omo ti won bi si Ilu oyinbo tabi ile

                                       

okeere ti won gbe wa ile.

 

IGBELEWON

  1. Daruko  ohun marun-un ninu ohun elo isomoloruko ki o si salaye bi won se n lo won.
  2. Ko apeere oruko marun-un ninu oruko ile Yoruba pelu alaye.

 

IWE AKATILEWA

 Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 101-119.

 

ITUPALE EWI APILEKO

Ewi je awon akojopo ijinle oro ti a ko sile tabi eyi ti a n ke pelu ohun didun. A maa n ko ni ila si ila ni. A ki i ko o bi aroko. ni abe ewi ni ati maa n se agbeyewo akanlo ede ayaworan  akanlo ede ayaworan tumo si awon eroja ti o maa n mu ki ewi dun daadaa. Apeere won ni: awitunwi, asorege/ asodun, owe, akanlo ede, akude gbolohun, afiwe.

 AWITUNWI: ninu awitun ni a ti maa n tenumo oro ju eekan lo. A le pe oro bi eemeji tabi eemeta. Awiunwi eleyoro oro wa, akude gbolohun wa

ASOREGE/ASODUN: eyi ni ki a maa pon nnkan ju bi o se ye lo. Won le wi pe, a se inawo ti aye gbo orun si mo. ounje po bi ile bi eni. Eniyan po nibe bi yanrin eti okun.

OWE: Yoruba bo won ni owe lesin oro, oro lesin owe, bo oro ba sonu owe ni a fi maa n wa. owe je ona ti a fi maa n mo bi eniyan so gbo ede Yoruba to.

AKANLO EDE: Yoruba ki i fi gbogbo enu soro. Won maa n pe oro so ni. Awon agba le wi pe o feraku. Itumo eyi ni wi pe onitohun ti loyun. Baba agba tit a teru nipa tumo si wi pe baba agba ti ku.

IFORODARA: ninu iforodara ni won ti maa n fi oro da lorisiirisii. Fun apeere:

Aso funfun ma funfun ni funfun

O ti le funfun ni funfun ki funfun ju.

Yaya ki ba ti je eran oya

Bi ki i ba se iya Yaya ti n tae ran oya ni Moniya.

IGBELEWON

Se itupale asayan iwe ewi kin-in-ni ti ijoba yan.

 APAPO IGBELEWON.

  1. Ko apeere oro oruko mewaa sile
  2. Ko apeere oro-oruko marun fun oruko abiso, amutoruwa, inagije.
  3.  Ko apeere akanlo ede ayaworan mefa.

ISE AMURELE.

  1. Salako gbe igunnu. Ew ni oro oruko ti o n se ise oluwa?[a] Salako [b] Salako gbe [d] Igunnu.
  2. Oro-oruko a maa sise oluwa, ..... ati eyan [a] ise [b] aatokun [d] abo.
  3. Baba pe mi. Abo inu gbolohun yii ni ------- [a] baba [b] pe [d] mi.
  4. Ewo ni ki i se ara won? Taiwo, Kehinde, ige, Ojo .........[a] Olugbodi [b] Idoha [d] Salako.
  5. Oruko ti o je mo ise ilu ni ....... [a] Alayande [b] Oje kunle [d] Malamo.

 APA  KEJI

  1. Ko apeere oruko amutorunwa marun-un sile.
  2. Ko apeere abuda oro oruko marun-n sile pelu apeere mejimeji.