Skip to content

We use essential cookies to sign you in and remember your settings. With your permission we also use analytics cookies to understand how the site is used. See our privacy policy or fine-tune this anytime at cookie settings.

SubjectFree lesson

Aayan Ogbufo.

ClassNotes Team 6 MIN READUPDATED 14 JUL 2026

OSE KEJI

Aayan  Ogbufo

 

AKOONU

Aayan ogbufo ni ise titumo ede kan si ede miiran. Ki ogbufo to le kogo ja ninu itumo ede, o gbodo mo tifun tedo ede Geesi , ki o si le tusu ede Yoruba naa de isale ikoko.

Kii se gbogbo oro inu ede kan naa le tumo si ode miiran.

A ko gbodo mu gbolohun ni okookan lati tumo, sise bee yoo so ewa ati itumo iru ayoka bee nu.

A ko gbodo mu oro ni eyo kookan lati tumo, ti a ba se bee yoo so itumo oro ti a fe tu nu.

Akaye ati akatunka ayoka se pataki ki o to le se ogbufo to peye.  Rii pe o lo akoto to muna doko eyi ni yoo je ki o see ka.

Lilo itumo erefee ko bojumu, eyi ko ni fun wa ni itumo ti o kun, itumo ijinle ni o ye ogbufo.

O san ki ogbufo lo oruko ti o wa ninu ayoka.

Eyi ni aayan ogbufo sise laarin awon akekoo ninu kilaasi.

 

Please bury the hatchet

Jowo fiye denu

He who fight and runs away leaves to fight the other day

Agbo to feyinrin, agbara lo lo mu wa.

 

Time and tide wait for no man

Akoko ati igba ko duro de enikan.

 

Paddle your own canoe

Gbo tire       

 

They may have been drumming

Won ti le maa lu ilu

 

He came in reluctantly

O wole tikotiko

 

Tumo ayoka yii si ede Yoruba

 

Birds take great trouble to give their young a good start in life.  The female bird lays a hard-shelled egg from which the young animal gradually develops with supplies of goods and air.  In most cases, the eggs are laid in a carefully prepared nest hidden from enemies or out of their reach.

 

Awon eye a maa se opo wahala lati fun awon omo won ni ibere rere ni aye. Iya eye a maa ye eyin eleepo lile.

 

Ninu eyin yii ni awon omo eye yo ti maa ri ounje ati afefe ti yo mu won maa gbora diedie.  Ni opolopo igba inu ite ti won farablae ko ti o sa pamo fun ota ni won maa n ye won si.

Don’t give it a chance

When problem comes

Don’t give it a chance

When joy comes

Rejoice moderately

Joy is a fragile thing

IGBELEWON

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Corpromutt (Publishers) Nigeria Ltd Oju Iwe 234-254.

ASA ISINKU NI ILE YORUBA

Awon Yoruba gbagbo pe gbogbo wa ni a da agbada iku,won a ni ‘ma forum yo mi gbogbo wa la jo n lo.’atomode atagba ko si eni ti ko ni ku,gbogbo wa la je gbese iku.Ki Olorun ko fi iku rere pa ni.

Awon Yoruba gbagbo pe bi eniyan ba ku yoo lo si orun, yala rere tabi orun apaadi.

 

AWON ONA TI A N GBA SIN ORISIIRISII OKU.

Ki Edumare ki o fi iku ire pa gbogbo wa bi a ti n sin oku kookan da lori eni ti o je ati iru iku ti o pa eni bee. Die ninu iru re niwonyii.

Eni ti sango pa.                Awon mogba nii se etutu  sisin re.

Eni ti sanponna pa            inu igbo ni won maa n sin-in si awon adahunse ni Si n se etutu sisin re.

Eni ti o ku sinu odo           eti odo ti o ku si ni won maa n sin–in si, awon  alawo ni si n se etutu re.

Eni ti o ku  toyuntoyun      awon oloro nii se etutu sisin re.

Adete                              awon ogbontarigi adahunse ni i se etutu sisin re, inu

                                      Igbo ni won a sin-in si, won a si sun gbogbo nnkan Ini re.

Eni ti o pokunso                Awon onimole ni i sin in,idi igi ti o pokunso si naa ni won o sin in si.

Abuke                              Awon babalawo ati adahunse ni i se etutu sinsin re,   

                                       Inu igbo ni won sin in si, ninu ikoko,won a si sin

                                       Gbogbo nnkan ini re mo pelu.

Babalawo                          awon agba awo ni i se etutu sisin oku babalawo        

 pelu eye ti o ga ti won yoo fi se etutu lati yose re kuro ninu egbe awo.

Ode                                 awon ode nii se ayeye oku ode sisin,oro Pataki ti

Won ni lati se fun un ni sisipa ode ti a mo si ‘ ikopa ode’ eyi ni etutu ti won maa  n se ki awon eran ti ode naa ti pa nigba aye re ma baa hun un,ki o sile je ki awon ode to ku laye maa ri eranko.

Onilu                                awon onilu nii se etutu onilu lati yowo elegbe won

                                                ti o ti ku kuro ninu egbe ki awon to ku le maa ri se.

Alagbede                                   Awon alagbede nii se oro igbeyin fun oku alagbede

                                                lati yowo re kuro ninu egbe.Inu ile aro ti alagbede

                                                naa ti n sise ki o to ku ni a ti maa n saba se etutu

                                                Ikeyin yii.

Yato si gbogbo awon wonyii,awon Yoruba a maa ro oku paapaa eyi ti o ba je oku oroju ti

won gba pe iku re kii se lasan,awon agba adahunse tabi oloogun ni o maa n ro oku, ki

won to gbe e si koto, riro yii lo maa je ki o se iku pa eni ti o pa a.   .

 

IGBELEWON : -

1. salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; - i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete, iv. Eni ti o pokunso.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo,Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Oju iwe 1-35 Corpromutt (Publishers) Nigeria Ltd.

APAPO IGBELEWON

1. salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; - i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete, iv. Eni ti o pokunso.

2. Ko aroko lori ‘ojo kan ti o ko le gbagbe’

salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; - i. eni toku somi, ii. Eni ti sango pa. iii. Adete, iv. Eni ti o pokunso.

ISE ASETILEWA

  1. Intuition A. ironinu B. oye inu C. inu kan D. oye oju.
  2. Interpreter A. atufo B. onpade C. ogbufo D. olusoro.
  3. Compare A. fi kan B. fi ran C. fi gba D. fi we.
  4. Mood A. imulara B. ifarasin C. imoloju D. ifokase.
  5. Decide A. pinnu B. ronu C. ro D. so.

APA KEJI

  1. Tumo awon oro yii:
  1. Mislead
  2. Tammerer
  3. Competition
  4. Verify
  5. Deity.

Bawo ni won se n sin: abuke, oba, afin.