Skip to content

We use essential cookies to sign you in and remember your settings. With your permission we also use analytics cookies to understand how the site is used. See our privacy policy or fine-tune this anytime at cookie settings.

SubjectFree lesson

AROKO ONILETA

ClassNotes Team 6 MIN READUPDATED 13 JUN 2026

OSE KIN-IN-NI

AROKO ONILETA

AKOONU                                       

Orisii leta meji lo wa ninu ede Yoruba, awon naa ni:

          Leta Gbefe ati

          Leta Aigbagbefe.

Leta mejeeji ni o ni eto ati ilana ti a n gba ko won.

Leta gbefe ni leta ti a ko si obi, ara, ore, ebi, egbon, aburo tabi si eni ti a mo ri.

ILANA LETA GBEFE NI

  • kiko adiresi eni ti a ko leta si. (Eyi le je olooro tabi elebe ni owo otun oke leta naa).
  • Deeti
  • Ibere leta pelu ikini ibere. (Tunji bawo, Aunti mi, Baba mi owon, Mama mi owon. ikini ni o maa n bere leta.a le wi pe ‘ se alaafia ni o wa ati gbogbo ara ile.
  • Inu leta.
  • Ni ipari leta gbefe, a o dagbere fun eni ti a ko leta si pelu.apeere; - ire o, o digba. ‘ tire ni tooto’.
  • Oruko eni ti o ko leta ni o maa n gbeyin. Apeere Kola, Bolu, Tope, Seun.

Ninu leta gbefe aaye wa fun ikini, apara ati awada.

LETA AIGBAGBEFE.

Eyi ni leta ti a ko si ile-ise ijoba bii ile-ise amohun-maworan,ile-ise itewe,yunifasiti abbl.

Ninu leta aigbagbefe eni ti o di ipo kan mu ni a maa n ko leta si ki I se enikan ni pato.

  • ko si pe a n ki ni, sere tabi se awada ninu leta aigbagbefe ibi koko leta ni a maa n lo taara.
  • Adiresi meji ni o maa n wa ninu leta aigbagbefe,adiresi eni ti o ko leta ati eni ti a n ko leta si.A maa n mo ipo eni ti a n ko leta si.apeere,alaga,akowe,oga agba.
  • Ori-oro tabi akole maa n wa ninu leta aigbagbefe.
  • Inu  leta/koko ti a fe bog an-an ni a gbodo lo taara.
  • Ipari leta. ‘emi ni tiyin ni a gbodo fi pari.
  • Oruko eni ti o ko leta. Apeere:

 

 

LETA AIGBAGBEFE.

                                                                                                                                                  12 Adeoti Street,

                                                                                                                                                   Oyo,

                                                                                                                                                   23rd May 1996.

The Director,

Iwe Iroyin Yoruba press,

77, Kadara Street,

Lagos.

Olootu

IBEERE FUN IPO AKOWE ATEWE.

Koko inu leta.

                                                                                      

                                                                                                  Emi ni tiyin

                                                                                                                                                                                                 Adebisi Raheem.

 

IGBELEWON:

Salaye iyato to wa laarin leta gbefe ati aigbagbefe

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo,Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Oju iwe 1-35 Corpromutt (Publishers) Nigeria Ltd.

 

Deeti …………………

ETO ENI SI OGUN JIJE

    • Oriki
    • Ohun ti a n je logun
    • Ona ti a n gba pin Ogun
    • Opo Sisu ati Omo Ajemogun
    • Ire ati Ibi to ro mo Ogun Pipin
    •  Iyato laarin Ogun Iya ati Baba

AKOONU

Ogun ni gbogbo dukia ti oloogbe fi sile fun omo ati awon ebi.  Adura gbogbo obi ni pe ki won ri omo rere gbeyin won.

Oro ogun pipin yii gbelege pupo ni pataki julo, ogun baba lo gbelege julo nitori opolopo iyawo ti won maa n ni laye atijo. Baba – n – sinku ni o ni ase lori isinku ati ogun pipin

Awon ohun ti won maa n pin logun. Gbogbo ohun ti oku ni ni dukia. Bii

  • Ile
  • Ile
  • Oko
  • Iso
  • Iyawo

Gbogbo awon nnkan wonyi ni won maa n pin logun. Obinrin (Iyawo) ti oku fi sile naa ni a le su lopo fun aburo tabi molebi oku ti o ba kan-an gbongbon.

 

ONA TI A N GBA PIN OGUN

Ona meji ni won n gba pin ogun ni aye atijo. i. ori –o- jori ati ii.idi igi.

ORI- O-JORI -: eyi tumo si  pe ogun ti oloogbe ba fi sile ni won yoo pin ni deede fun gbogbo omo ti o bi.

IDI IGI-: bi oku ba ku laye atijo, ti o si ni iyawo pupo.  Idi igi ni won fi maa n pin ogun bee.  Iyawo to bi omo kan ati olomo mejo ogun kan naa ni won yoo pin fun awon mejeeji. Ireje maa n wa ninu ogun pipun. idi niyi ti ogun baba si fi lewu pupo nitori pe inu olomo mejo ko le dun si ogun ti won pin fun-un, koda won maa n se orogun si ara won lori ogun.

 

Iyato laarin ogun iya ati baba.  Ogun iya lo fi okan bale julo nitori pe ko si orogun ninu ogun iya. idi niyi ti won fi n paa lowe pe -  “Gbede bi ogun iya, anini lara ba ogun baba”.

 

Igbelewon

1a Kin ni ogun pinpin

b. Daruko awon ohun ti a n je logun.

 

Iwe Akatilewa

Imo Ede Asa ati Litireso SS3 o.i 200-203

Adakedajo.

 

APAPO IGBELEWON

1a. Kin ni ogun pinpin

b. Daruko awon ohun ti a n je logun.

2. Salaye iyato to wa laarin leta gbefe ati aigbagbefe

IBEERE

  1. Ko eya ara ifo mejo sile.
  2. Ko eya ara ifo afojuri mefa sile.
  3. Ko eya ara ifo aifojuri mefa sile.

ISE ASETILEWA

  1. Leta ti o maa n ni adiresi meji ni leta A. gbefe B. aigbefe C. asotan D. asapejuwe
  2. Leta ti a maa n bu owo lu ipari re ni A. gbefe B. aigbefe C. asotan D. asapejuwe
  3. ….. ni a maa n ko eni ti o sun mo wa A. gbefe B. aigbefe C. asotan D. asapejuwe
  4. Eni ti won maa n pe ni eni orisa ni A. eniyan dudu B. eni giga C. afin D. afinju
  5. ….. n sunkun oku akasoleri n sunkun ara won A. eniyan B. ara orun C. oku D. eni maa ku.

APA KEJI

  1. Salaye bi won se n sin:
  1. Adete
  2. Abuke
  3. Agba ode
  4. Eni ti Sango pa.