Loading...

EDE YORUBA JSS2 SECOND TERM

Subject Scheme & Timeline:

Please check through the topics down and be sure it conform with the scheme you are using.

OSE KIN-IN-NIONKA YORUBA (301- 500) Gege bi a ti a so seyin pe iyato diedie yoo ba onka 20, 40, 60, ati 80 ni kete ti a kuro lori igba (200). Fun apeere:20 okoo40 oji60 ota80 orin300 ni a n pe ni oodunrun.400 je irinwo ti 500 maa je eedegbeta (600-100)=500. 600 ni a pe ni egbeta (200 x 3). 300 oodunrun 320 okooleloodunrun 340 ojileloodunrun 360 otaleloodunrun 380 orinleloodunrun 400 irinwo 420 okoolerinwo 440 ojilerinwo
OSE KEJIAROSO ALAPEJUWEAKOONU: Itumo. Apeere.Aroso ni ohun ti a ro lati inu arojinle wa ti a fe ko sile. Orisiirisii aroso lo wa, a ni aroko oniroyin, onileta, alalaye, onisorogbesi, alapejuwe, alariyanjiyan.
OSE KETA.AROKO ALAPEJUWEAKOONU: Itumo. Apeere.Aroko ni ohun ti a ko sile lati inu arojinle wa fun elomiran lati ka a. Orisiirisii aroko lo wa, a ni aroko oniroyin, onileta, alalaye, onisorogbesi, alapejuwe, alariyanjiyan.AROKO ALAPEJUWEEyi je mo sise apejuwe eniyan, ibikan tabi ohun kan lona ti o se pekipeki nnkan naa. Tori a le so wi pe aroko alapejuwe ni aroko ti a fi n se apejuwe eniyan tabi ibi kan(Descriptive essay). Apejuwe wa gbodo fi han pe a mo ohun ti a n soro nipa re. Apeere ori oro aroko alapejuwe ni:- Ile baba mi Oja ilu mi
OSE KERINAROSO ASOTAN/ONIROYIN AKOONU: Itumo Apeere. Igbese. Aroso ni aroso iroyin ohun ti o sele ni oju wa tabi ti won so wa fun ti a n so iroyin naa fun elo miiran laisi si ayokuro tabi afikun. O ye ki eni ti yoo royin nnkan le royin finnifinni lona ti ko si nibe nigba ti isele naa sele yoo fi le fi oju inu wo nnkan naa bi igba ti oun gan alara fi oju se konge ohun naa ni. Die ninu awon ori oro ti a le ko aroso oniroyin le lori ni wonyi:- Ija igboro kan to soju mi Ijamba moto kan ti mo wa ninu re Ojo kan ti a ko le gbagbe Ayeye ojo ibi kan ti mo lo
OSE KARUN-UNAROKO ASOTAN/ONIROYIN AKOONU: Itumo Apeere. Igbese. Aroko ni ohun ti a ko sile lati inu arojinle wa fun elomiran lati ka a. Orisiirisii aroko lo wa, a ni aroko oniroyin, onileta, alalaye, onisorogbesi, alapejuwe, alariyanjiyan.Aroko oniroyin: ni a n pe ni aroko asotan. Iru aroko yii ni a ti maa n so itan isele ti a fi oju ri tabi eyi ti a kopa ninu re, tabi ti a gbo lati enu enikan. Aroko yii maa n so nipa ohun to ti sele seyin ni. Die ninu awon ori oro ti a le ko aroko oniroyin le lori ni wonyi:- Ija igboro kan to soju mi Ijamba moto kan ti mo wa ninu re Ojo kan ti a ko le gbagbe Ayeye ojo ibi kan ti mo lo
OSE KEFAAKAYEakaye ni ohun ti a ka ti o si ye wa yekeyeke. Ti a ba fe dahun ibeere ti o tele akaye, a gbodo fi ara bale daadaa ka akaye, a gbodo ka akaye ni eemeji. Leyin eyi ni o wo awon ibi ti ibeere ti jeyo ninu akaye. Leyi ni yoo dahun ibeere. Ti o ba ti dahun ibeere tan ni yoo tun wo boya idahun ba ibeere mu.
OSE KEJEAKAYE 1(Ka akaye yii ki o si dahun ibeere ti o tele)Ojo ko ti awon eegun yoo pidan ni ita Oba. Oba ati awon ijoye ati gbogbo awon ero ti pese wamuwamu si aaye won. Bee ni olukuluku awon eegun nla n ta okiti, won le awon eegun keekeeeke lese wa si ojude Oba. Ariwo n ta gee bee ni kaluku ti n lo juba niwaju Oba ki won to lo jokoo laaye won. Eyi ti o ba de keyin a si juba awon ti o ba niwaju ki o to jokoo. Sugbon okan ganta bayi de, se ni o lo jokoo ni tire leyin ti o ti ki Oba tan, ko tile naani awon ti o ba niwaju rara. Awon naa si kan oro re sinu. Won ni awon yoo maa wo ibi ti yoo ruu wo.
OSE KEJOAKAYE ONISOROGBESI ( Olu ati Aina pade arawon ni ile itura piremia ni Ilu Ibadan. Won ti ri arawon tipe die. Bayi ni won bere oro won.)Aina Olu, iwo niyen, e ma ku ojo meta.0lu Emi niyen o, lowo oko aaro.Aina Se ko si nnkan Olu? O da bi igba wi pe ara re fa die.Olu Ara mi da ko si nnkan to n se omo olorun. Bi ode ti ri naa ku ni.Aina Iyen o maa to o ro. Arun gbogbo aye niyen ( Leyin igba ti won joko ).Olu Aina, Iyawo ati awon omo nko?Aina Gbogbo won wa daadaa. Igba ti mo tile n bo ni oko mi n mura lati mu awon omo jade
OSE KESAN-AN.IWA OMOLUWABI Iwa omoluabi ni iwa ti o to ti o si ye ki eniyan ma hu. Iwa rere ti o ye ti o si to ki eniyan maa hu ninu ile, ninu ijo, ninu egbe ati laarin ilu ni a pe ni iwa omoluabi. Iru iwa bayi maa wopo laarin awon omo ile iwe. Ibowofagba, iwa iteriba, ikini, otito siso. Iranra eni lowo. Iru iwa bayi maa n mu ibasepo wa laarin ebi ara ore ni. Nitori naa iwa omoluabi ni iwa ti o to ti o si ye ki eniyan ma hu. Apeere iwa omoluabi ni awujo ni: Ikini Otito siso Iteriba Igboran Iwa iforiti Asa iranra eni lowo Iwa pele
OSE KEWAAGBOLOHUN EDE YORUBAgbolohun ni ipede ti o kun pelu itumo kikun. Orisii eya gbolohun meji ni o wa. Awon eya naa ni: (i) gbolohun ni ilana ihun ati (ii) gbolohun ni ilana ise tabi ise ti o n je. Gbolohun ni Ilana Ihun ni: gbolohun eleyo oro ise (abode), olopo oro ise (onibo) ati alakanpo. Gbolohun eleyo oro ise o maa n ni eyo oro ise kan. Apeere: ade pa eku. Gbolohun olopo oro ise: o maa n ni ju eyo oro ise kan lo. Apeere: Kunle sare tete lo pon omi Gbolohun alakanpo: o maa n gbolohun meji ninu. O si maa ni oro asopo ninu pelu. Apeere: Apeere: Olu je buredi ati eyin.

Subject Reviews:

Average Rating0
    0 Ratings
    Details
    5 Stars0%0
    4 Stars0%0
    3 Stars0%0
    2 Stars0%0
    1 Stars0%0

    No reviews yet.

    Also available in Bundles